Iku agbabọọlu
ikọ Rangers International ti ilu Enugu Ifeanyi George ṣe ni laanu gan na, bayii
ni minisita fun ere idaraya ati ọrọ ọdọ, Sunday Dare ṣe n kẹdun
Ifeanyi di
oloogbe lẹni ọdun mẹrindinlọgbọn pẹlu awọn akẹgbẹ rẹ meji, Emmanuel Ogbu ati
Eteka Gabrielinu ijamba ọkọ to ṣẹlẹ lanaa ọjọ Aiku.
Iroyin ti a
gbọ ni pe ọkọ ayọkẹlẹ ti wọn wa ninu rẹ lo lọ fori sọ ọkọ nla akẹru kan nibi ti
o duro si.
Lopopona
Agbor ni ipinlẹ Edo ni ijamba ọkọ ọhun ti ṣẹlẹ nigba ti George ati awọn akẹgbẹ
rẹ n rinrin ajo ni opopona ilu Onitsha si Eko.
Alukoro ẹgbẹ
agbabọọlu Rangers ṣalaye pe awọn agbabọọlu naa rinrin ajo lọ si ilu Eko lẹyin
ti idije liigi Naijiria(NPFL) ti di siso rọ ki ijamba naa to ṣẹlẹ.
Ajọ ẹṣọ oju
popo FRSC sọ pe awọn mẹtẹẹta lo ja laisi lojuna ti ijamba ọkọ naa ṣẹlẹ tan.
Minisita ni o
ṣeni laanu pe pe awọn mejeeji ṣagbako iku ojiji lai le jẹ ohun ti wọn fẹ jẹ
laye.
Minisita
gbadura si Eleduwa pe ko tu awọn ẹbi awọn agbabọọlu mejeeji ninu, o ni oun naa
kẹdun awọn agbabọọlu mejeeji.
Ẹwẹ, ajọ to n
ri si ere bọọlu afẹsẹgba ni Naijiria, NFF sọ loju opo Twitter rẹ pe ibanujẹ nla
ni iku awọn agbabọọlu mejeeji jẹ.
NFF kẹdun
pẹlu ẹbi awọn oloogbe naa ati ẹgbẹ agbabọọlu Rangers Intl, ajọ naa gbadura pe
ki Eleduwa tẹ wọn si afẹfẹ rere.
Lati: BBC
No comments:
Post a Comment