NITORI ALAWE: FAYẸMI PAROKO RANṢẸ S'AWỌN ỌBA EKITI, L'AWỌN ỌBA EKITI BA KỌJU IJA SI ALAAFIN ỌYỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, March 15, 2020

NITORI ALAWE: FAYẸMI PAROKO RANṢẸ S'AWỌN ỌBA EKITI, L'AWỌN ỌBA EKITI BA KỌJU IJA SI ALAAFIN ỌYỌ

* Ọrọ ko ri bẹẹ rara - Fayẹmi bẹ Alaafin

Pẹlu bi nnkan ṣe n lọ yii, afaimọ ki wahala to n ṣẹlẹ laarin awọn ọba alaye n'ipinlẹ Ekiti ati Gomina Kayọde Fayẹmi t'ipinlẹ naa ma tun gba ọna mi-in yọ lori b'awọn ọba kan tun ṣe dide ogun si Alaafin Ọyọ, Ọba Lamidi Adeyẹmi.

Laipẹ yii Gomina ipinlẹ Ekiti, Kayọde Fayẹmi yan Ọba Alawe tilu Ilawe-Ekiti, Ọba Adebanji Alabi gẹgẹ alaga igbimọ awọn lọba-lọba n'ipinlẹ Ekiti, eyi ti wọn ni ko dun mọ awọn ọba kan ninu.

Bi Gomina Fayẹmi ṣe kede Ọba Alabi l'awọn ọba ti inu wọn ko dun si i ti bẹrẹ si i fẹhonu han wi pe awọn ko ni i gba, ayafi ki Gomina tun ipinu rẹ ṣe nitori pe ipo naa ko tọ si Ọba Alabi rara.

Awọn ọna naa la gbọ pe wọn ṣe ipade laarin ara wọn wi pe bi Gomina Fayẹmi ko ba ti tun ero rẹ pa nipa bo ṣe yan Ọba Alabi, wọn l'awọn ko ni i yọju sibi eto tabi ipade ti Gomina ba n ṣe, paapaa ti Ọba Alabi naa ba ti wa nibẹ.

Bẹẹ ni wọn tun sọ pe awọn ko ni i yọju sipade igbimọ lọba-lọba to ba n waye n'ipinlẹ Ekiti, ayafi bi igbesẹ mi-in ba waye lati yan alaga tuntun.

Gbogbo awọn eto t'ijọba Ekiti n gbe kalẹ la gbọ pe awọn ọba naa ko yọju, ti wọn si lo n kan awọn agbaagba ilu, to fi mọ Gomina Fayẹmi funra rẹ ninu, idi ni yii ti wọn loo fi paṣẹ pe ki ileeṣẹ to n ri sọrọ oye jijẹ n'ipinlẹ naa kọ'we ranṣẹ s'awọn ọba naa lati sọ idi ti wọn ki i ṣe n yọju s'awọn ipade ati eto t'ijọba n ṣe.

Image may contain: one or more people and people sittingNinu lẹta naa ni Fayẹmi tun ti sọ pe k'awọn ọba naa ta a gbọ pe wọn ko ju mọkanla lọ tun sọ idi pataki ti wọn ko fi fẹ ki ọba Alabi jẹ alaga igbimọ lọba-lọba, to si ni wọn gbọdọ dahun laarin wakati mejilelaadọrin (72hours).

Bi lẹta naa ṣe jade sita, ni wọn l'awọn kan ti n gbe e kaakiri wi pe Fayẹmi n dunkooko lati gba ade lori awọn ọba kan, iyẹn awọn ọba ti wọn ko ba ṣe tiẹ.

Loju ẹsẹ ni agbenusọ fun Gomina Fayẹmi lori ọrọ iroyin, Ọgbẹni Yinka Ọlabọde ti sọrọ jade wi pe ko si otitọ ninu ahesọ t'awọn eeyan n gbe kaakiri wi pe Gomina Fayẹmi fẹ ẹ gba ade lori awọn ọba kan.

O l'awọn ọba mọkanla pere ni Gomina Fayẹmi fi lẹta ranṣẹ si lati dahun ibeere, ko si kan awọn Pẹlupẹlu mẹrindinlogun ti wọn n gbe kaakiri rara.

Ni kete ti lẹta yii ti jade sita, to si ti tẹ Alaafin Ọyọ, Ọba Lamidi Adeyẹmi lọwọ l'oun naa ti dide, to si paroko buruku ranṣẹ si Gomina Fayẹmi wi pe o gbọdọ bọwọ fun ori ade, ati pe ko gbọdọ fi ipo oṣẹlu da si ọrọ igbimọ lọba-lọba.

Ninu lẹta ti Alaafin kọ lorukọ awọn ọba alaye ilẹ Yoruba bi i Ọọni le-Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi; Awujalẹ tilẹ Ijeẹbu, Ọba Sikiru Adetọna; ati Alake ilẹ Ẹgba, Ọba Adedọtun Gbadebọ lo ti sọ pe n'iwọn igba t'ọrọ naa ti wa n'ile-ẹjọ, ko yẹ ki Gomina Fayẹmi tun maa dunkooko mọ awọn Ọba kankan mọ.

Alaafin sọ pe oun bani lọkan jẹ pupọ ni pe Gomina Fayẹmi tun n da si ọrọ awọn ọba pẹlu niwọn igba ti ile-ẹjọ ti wa lori ọrọ naa lati ba wọn yanju ẹ, to si l'awọn Ọba wọnyii ki i ṣe ọba kereje-kereje rara, Ọba alaye n'ilẹ Yoruba ni wọn.
O l'aṣoju awọn oriṣa l'awọn Ọba jẹ, ti ipo naa si jẹ ipo awọn alalẹ ati ti ẹmi, ati pe awọn ni wọn ba le ori ohun gbogbo ati ilẹ. Bẹẹ lo l'oun ko yoo gba Fayẹmi lamọnran lati yọwọ kuro lori ọrọ naa, ko si fi silẹ saaye wọn.

Bi lẹta yi ṣe jade sita, to si ti n kaakiri ori ayelujara l'awọn to ri i ti bẹrẹ si i sọ oriṣiriṣi to yẹ wọn. B'awọn kan ṣe n bu ẹnu atẹlu lẹta yii, bẹẹ l'awọn kan n gbe oṣuba kare fun Alaafin, ti wọn si lo o yẹ Gomina Fayẹmi tete gbe igbesẹ to yẹ le e lori ko to o pẹ ju.

A copy of Ekiti State Traditional Council letter to Alaafin of Oyo, Oba Lamidi Adeyemi
Lẹta naa re e
Eyi to tun wa a jẹ iyalẹnu pupọ ni b'awọn ọba kan n'ipinlẹ tun ṣe dide lati tako Alaafin Ọyọ lori lori lẹta to kọ, ti wọn si ni ko si nnkan to kan an pẹlu ọrọ Ekiti, wọn ni ko gbajumọ ọrọ Ọyọ to jẹ Ọba le lori.

A  copy of Ekiti State Traditional Council letter to Alaafin of Oyo, Oba Lamidi Adeyemi 
Awọn Ọba yii lo jẹ pe Gomina Ṣeyi Makinde ni wọn dari lẹta naa si wi pe ko kilọ fun Alaafin Ọyọ lati gbe ẹnu rẹ dakẹ, ko si ye e da si ọrọ ti ko kan an rara, ati pe bi ko ba dakẹ, yoo kan abuku ti o lero.

Wọn ni Alaafin ko gbọdọ maa sọ pe oun l'aṣẹ lori awọn Ọba Ekiti n'itori pe ko si lara Ọyọ ti Alaafin le maa da si ọrọ rẹ. Bẹẹ ni wọn tu sọ pe awọn ọrọ ti Alaafin kọ sinu lẹta rẹ yatọ patapata si ohun to n ṣẹlẹ l'Ekiti.

Bi ọrọ naa ṣe n ja rain-rain nilẹ, ti Gomina Fayẹmi ri i pe ori oun ni gbogbo ọrọ naa yoo da le lẹyin-o-rẹyin lo muu gbera laarọ onii, Aiku ti i ṣe Sannde, to si gba Aafin ọyọ lọ lati lọ ọ sọ bi ọrọ naa ṣe jẹ.

Image may contain: 1 person, sittingẸkunrẹrẹ ohun ti Gomina Fayẹmi ba Alaafin sọ n bọ laipẹ. Ẹ ku oju lọna.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI