Ṣe ni gbogbo ilu Ṣasgamu n'ipinlẹ Ogun pa lọlọ lonii, nigba ti wọn ṣe eto isinku gbajumọ Ọnọrebu to ku laipẹ yii, iyẹn Ọnọrebu Yinka Mafẹ to jẹ olori ọmọ ile igbimọ aṣofin to pọ ju ninu ijọba to kọja yii.
Lara awọn to wa nibi eto isinku naa ni Sẹnetọ Ibikunle Amosun, Yetunde Ọnanuga to jẹ igbakeji gomina ana n'ipinlẹ Ogun, Amofin Taiwo Adeoluwa to jẹ akọwe ijọba Amosun, Ọnọbe AbdulKabir Akinlade at'awọn mi-in.
Ẹṣe ko gbero rara, ko da, ṣe ni omije n pe omije ran niṣẹ, ki Ọlọrun ba wa tẹ oloogbe naa si afẹfẹ rere.
No comments:
Post a Comment