Lati d'ẹkun itankalẹ si aarun aṣekupani ti Coronavirus, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ẹnugu ti kede sita wi pe awọn ti ṣetan lati tu awọn to wa latimọle silẹ, ati pe ko ni s'anfaani lati maa ti awọn eeyan mọ'le n'iwọn igba ti ẹṣẹ wọn ko ba ti lẹsẹ nilẹ.
Alukoro ọlọpaa ipinlẹ naa, Daniel Ndukwe lo fi ọrọ sita ninu atẹjade to gbe sita laipẹ yii, to si l'awọn ọlọpaa ko gbọdọ lọ maa mu awọn eeyan bi i ti tẹlẹ yatọ si awọn ọdaran pọmbele.
O ni ọna kan ṣoṣo lati dẹkun itankalẹ aarun Coronavirus ni pe ki wọn ye e mu awọn eeyan ti ọrọ wọn ko ba ti kọja nnkan ti wọn n f'oju wọn ba ile ẹjọ.
Bẹẹ lo tun sọ pe ki gbogbo ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to ba wa n'ipinlẹ naa tu awọn ti wọn kan ti mọle silẹ, paapaa awọn ti wọn n reti eeyan lati gba beeli wọn silẹ.
O tun fi kun un wi pe yatọ si awọn ti f'ẹsun apaayan, idigunjale, ijinigbe, ifipabanilopọ at'awọn mi-in kan, wọn ko gbọdọ mu ẹnikẹni, ati pe wọn gbọdọ ṣe ayẹwo kikun fun awọn ti wọn ba mu fun ẹsun wọnyi daadaa ki wọn to o ti wọn mọ'le.
O tun fi awọn nọmba pajawiri sita wi pe k'awọn eeyan wa ni ofintoto loore-koore. Awọn nọmba naa niwọnyi; 08032003702,
08075390882 or 08086671202.
No comments:
Post a Comment