Kani kí i ṣe pé digbi ni Ọlọ́run wá lẹ́yìn igbá-kejì Ààrẹ orílẹ̀-èdè yìí, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo ni, bóyá ohun tí a ń kọ yìí kọ ní a ó bá máa kọ, pẹ̀lú bí ọkọ akọwọrin ẹ ṣe pàdé ijamba òjìji.
Àárọ̀ onii tí í ṣe Fraide ni Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo gbéra láti lọ síbi ìpàdé kan n'ilu Eko, papakọ ofurufu ti Nnamdi Azikwe tó wà n'ilu Abuja lo sì ti fẹ́ lọ wọ baluu agberapa tí yóò gbé e.
Ojú ọ̀nà là gbọ pé nnkan ti yiwọ fún ọkàn lára àwọn ẹṣọ ààbò nínú ikọ akọwọrin ẹ, ìyẹn ọlọ́pàá tí wọn pé orúkọ ẹ ní Ali Gomina, tòun wá lórí ọkada agberapa {Power Bike}, tí wọn sì ni ṣe ló ṣubú yakata sáàárín òpópónà.
Òjijì ti wọn ni ijamba náà jẹ lo mú kí àwọn mọto tó wà lẹ́yìn rẹ tẹ ẹ, tí wọn sì gba ara wọn, tó fi mọ mọto tí igbá-kejì Ààrẹ náà wá nínú ẹ.
Bo tilẹ̀ jẹ́ pé ṣe ni wọn fẹ ẹ ṣe ijamba náà ni òkú òru, ṣùgbọ́n ojutaye tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà tí wáyé ní kó faaye gba a.
Ìdí re e tí agbẹnusọ igbakeji Ààrẹ, Ọgbẹni Laolu Akande ṣe fi ìròyìn ibanujẹ náà síta, tó sì lo ó jẹ ohun ibanujẹ wí pé ijamba náà mú Gomina lọ.
Ali Gomina tí wọn lo ó bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ ní wọn sọ pé ọmọdun marundinlaadọta {45} ni, tí wọn sì ṣàpèjúwe rẹ gẹ́gẹ́ bí akíkanjú ọlọ́pàá tó mọ iṣẹ rẹ dáadáa.
Ọjọgbọn Ọṣinbajo tí ranṣẹ ibanikẹdun sì ìdílé Gomina tí wọn loo fi ìyàwó, àwọn ọmọ àtàwọn ẹbi silẹ lọ.
Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ni wọn ń bá Ọjọgbọn Ọṣinbajo dupẹ títí di asiko ti a kọ ìròyìn yìí tán.
No comments:
Post a Comment