Latigba t'jọba orilẹ-ede Naijiria labẹ Aarẹ Muhammadu Buhari ti kede sita wi pe ki owo jaala epo bẹntiroolu lọ silẹ l'ọpọ awọn ọmọ orilẹ-ede yii ti n dunnu wi pe asiko igbadun l'awọn wa yii.
Bẹrẹ lati ọjọ kọkandinlogun ana, iyẹn Ọjọbọ ti i ṣe Tọside n'ijọba sọ pe ki eto naa bẹrẹ, ati pe ki gbogbo ileepo patapata, jakejado yi mita (metre) epo wọn kuro ni N145 to wa tẹlẹ si N125 naira bayii.
Ko si nnkan meji ti ijọba fi gbe aṣẹ yii kalẹ bi ko ṣe ti ọrọ aje agbaye to ti lọ silẹ patapata lori ti aarun Coronavirus to n ṣeku p'awọn eeyan kaakiri agbaye.
Si iyalẹnu lo jẹ pe titi di asiko ta a fi kọ iroyin yii tan, ọpọ awọn ileepo kaakiri ipinlẹ Ogun, to fi mọ Abẹokuta to jẹ olu-ilu ipinlẹ Ogun ni wọn kọ lati tẹle ilana ati aṣẹ ijọba.
Lara awọn ileepo to kọ ni Ayọmide to wa ni Iyana-Mọṣuari; Oando to wa ni Ijaye; Akinmade to wa ni Kemta; Moore, Energy to wa ni Abiọla-Way; Sunny Yinka, Ebenfem to wa ni Leme at'awọn mi-in.
Ohun ti ọpọ awọn to n ra epo n tẹnumọ l'asiko yii ni pe kani ṣe n'ijọba paṣẹ wi pe ki owo epo lọ s'oke, ko ni i to iṣẹju meji ti gbogbo wọn yoo ti yi mita wọn, ṣugbọn ni bayii, ṣe la gbọ pe wọn kọ lati tẹle aṣẹ ijọba apapọ.
Lara awọn araalu to b'AWIKONKO sọrọ sọ pe o yẹ ki awọn oṣiṣẹ DPR ti bẹrẹ si i lọ kaakiri lati maa fi ofin naa mulẹ nitori pe kosẹni to kọja ofin ati aṣẹ ijọba.
No comments:
Post a Comment