Lonii ni Gomina ipinlẹ Kaduna, Nasir
El-Rufai ṣe abẹwo si Emir tilu Kano, Sanusi Lamido Sanusi ti wọn rọ loye laipẹ yii n'ilu Awe, ipinlẹ Nassarawa.
Ọpọ awọn ti wọn ri nnkan to ṣẹlẹ yii lo ya lẹnu pupọ, ti wọn si n sọ pe ọrọ oṣelu ni wọn lọ ọ sọ.
Ilu Awe ni Gomina Ganduje tare Sanusi si, ni kete to rọ ọ loye, to si pa a laṣẹ wi pe ibẹ ni yoo wa.
Ṣaaju asiko yii ni El-Rufai ti kede sita wi pe oun wa loju ọna Awe, nibi ti Sanusi Lamido wa lati lọ ki i.
Bẹ o ba gbagbe, ni kete ti ijọba Kano yọ Sanusi nipo gẹgẹ bi Emir ni ijọba ipinlẹ Kaduna kede rẹ gẹgẹ bi ọga agba pata fun fasiti ipinlẹ Kano, ati Kaduna Investment Promotion
Agency, KADIPA.
No comments:
Post a Comment