Gbajugbaja oṣere tiata oloyinbo nni, Susan Peters ti pariwo sita wi pe o ye ki wọn fi aaye silẹ f'awọn obinrin, paapaa iyawo ile lati ni ọkọ meji lẹẹkan ṣoṣo, k'awọn naa si le wa ni itura.
Susan to ti farahan ninu ọpọ fiimu orilẹ-ede yii lo sọrọ naa lori ikanni ayelujara ti Instagram rẹ laipẹ yii wi pe o yẹ ki ofin ti yoo fun awọn obinrin naa laaye lati yan ọkọ meji, to si ni obinrin naa yoo ni ẹni ti yoo rọ ọ lẹkun bi ọkọ rẹ ba kọ ọ silẹ lojiji.
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe "O yẹ ki wọn f'awọn obinrin lanfaani lati fẹ ọkọ meji, nitori asiko ti ara ba san", iyẹn ni pe bi ọkọ rẹ ba kọ ọ silẹ, to si le e jade kuro n'ile.
No comments:
Post a Comment