Wẹ́rẹ́ báyìí ni ìròyìn náà jáde sigboro ayé wí pé gbajugbaja oṣere tíátà nnì, Ọgbẹni Kayọde Odumosu tí ọ̀pọ̀ àwọn olólùfẹ́ tíátà mọ sì Pa Kasumu tí kú lẹ́yìn àìsàn rampẹ tí wọn loo dá a dubulẹ láti bí ọdún mélòó kan sẹ́yìn.
Ọ̀pọ̀ àwọn tí wọn mọ Baba yìí ni wọn fẹ́ràn rẹ gidigidi torí pé ọna tó gbé ìṣẹ tíátà tí ẹ gbà yàtọ̀ gedengbe sì táwọn yòókù, tó sì mú kó gbayii láwùjọ oṣere.
Láti bí ọdún mélòó kan sẹ́yìn ni Pa Kasumu tí wá lórí idubẹ aisan, tó sì jẹ pe àìsàn ojú pẹlu awọn nnkan tó ń ṣe é kò tó o ku.
Pa Kasumu tọrọ iranlọwọ láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlẹyinju àánú káàkiri àgbáyé, tó sì jẹ pe iwọnba ni owo tó rí gbà.
Bi ọdún 2019 ṣe ń parí lọ ní Pa Kasumu gba ile ipagọ tí ṣọọṣi Ridiimu tí Baba Adeboye lọ fún àdúrà, nibẹ lo sì ti sọ pé àdúrà nìkan lòun nílò, kí í ṣe owó.
Ohun táwọn èèyàn sọ nígbà náà ni pé Pa Kasumu kò tún fẹ ẹ dá àwọn èèyàn láàmú láti máa tọrọ owó lọ́wọ́ wọn, pàápàá bo ṣe jẹ́ pé àwọn èèyàn kò ṣetan láti dawo fún un.
Ọsibitu tí wọn tí ń tọju Pa Kasumu lo dakẹ sì laaarọ òní ọjọ́ kinni-ín oṣù kẹta ọdún 2020.
Folukẹ Daramọla, ọkàn lára àwọn oṣerebinrin lo gbé ìròyìn náà sórí ìkànnì ayélujára tí Instagram rẹ lọsan òní, tó sì jẹ kò di mímọ pé ọkàn lára àwọn mọlẹbi olóògbé náà lọ tú àṣírí yìí.
Orí kẹkẹ ni Pasumu wá láti bí ọdún méjì sẹ́yìn, tí wọn ń gbé e káàkiri.
Jù gbogbo ẹ lọ, àìsàn tó dá Pa Kasumu dubulẹ láti bí ọdún mélòó kan sẹ́yìn náà padà rán án lọ sọrun, kí Ọlọ́run tẹ ẹ sì afẹ́fẹ́ rere. Amin
No comments:
Post a Comment