CORONAVIRUS: MFM, REDEEMED AT'AWỌN ṢỌỌṢI MI-IN WỌGILE ISIN ỌJỌ SANDE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, March 20, 2020

CORONAVIRUS: MFM, REDEEMED AT'AWỌN ṢỌỌṢI MI-IN WỌGILE ISIN ỌJỌ SANDE

Fun igba akọkọ, ọpọ awọn ṣọọṣi t'awọn eeyan ko lero ni wọn ti paṣẹ f'awọn ọmọ ijọ wọn wi pe ki wọn jokoo sile wọn lori aarun aṣekupani ti Coronavirus to n ja rain-rain kaakiri agbaye.

Lara awọn ṣọọṣi to kede wi pe k'awọn ọmọ ijọ wọn jokoo sile Mountain of Fire and Miracles Ministries to jẹ ti Ọmọwe Daniel Olukọya; Redeemed Christian Church of God ti Pasitọ Adejare Adeboye.

Deeper Christian Life Bible Church ti Pasitọ Williams Kumuyi; Synagogue Church Of All Nations ti Pasitọ Temitọpẹ Joṣua at'awọn mi-in ni wọn ti kede wi pe k'awọn eeyan duro nile lori aṣẹ t'ijọba Eko ati Ogun pa wi pe ko gbọdọ si ipejọpọ ti yoo le ni aadọta eeyan.

Wọn ni yatọ si isin ọjọ Sande, ko gbọdọ si isin aarin ọsẹ bi ẹkọ bibeli, akanṣe adura, itusilẹ tabi oniruuru ipade kankan to gbọdọ waye.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI