Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti f'idi rẹ mulẹ wi pe ọwọ awọn ti tẹ awọn ọrẹ mẹta ti wọn n fi aṣọ ṣọja lu awọn araalu ni jibiti, ti wọn si tun fi n dunkooko mọ awọn eeyan kaakiri ilu.
Ọjọ Ẹti ti i ṣe Fraide, iyẹn ọjọ kẹta oṣu yii la gbọ pe ọwọ tẹ awọn ọrẹ mẹta naa ti wọn pe orukọ wọn ni Jacob Onebi, Ọlabọde
Oluwaṣeun ati Ọlanrewaju Adebayọ. Ilu Agbado, ipinlẹ Ogun lọwọ palaba wọn ti segi.
Awọn kan ti wọn fura s'awọn eeyan la gbọ pe wọn lọọ ta awọn ọlọpaa lolobo, ti wọn si ṣe iwadii wọn daadaa, ko to o di pe wọn lọọ ko wọn.
174 Battalion to wa n'ilu Ikorodu l'awọn eeyan naa l'awọn ti n ṣiṣẹ n'igba tọwọ tẹ wọn, ṣugbọn lẹyin iwadii awọn ọlọpaa ni wọn ri i pe meji ninu wọn lo ti ṣiṣẹ ṣọja ri, ti wọn si ti le wọn danu tipẹ.
Ẹni kan yooku la gbọ pe ko ṣiṣẹ naa ri, ṣugbọn ti pe e mọra lati jọ maa lu awọn eeyan ni jibiti.
Ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Kenneth Ebrimson ti sọ pe ki ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n ṣe ofintoto tẹsiwaju lori iwadii, bẹẹ lo sọ pe awọn eeyan naa ko nii lọ lai jiya ẹṣẹ wọn labẹ ofin.
No comments:
Post a Comment