AYÉ Ò! PETER FATOMILỌLA, AGBA Ọ̀JẸ̀ NIDI IṢẸ́ TÍÁTÀ SỌRỌ ÀBÙKÙ SI ALÁÀFIN Ọ̀YỌ́, O LOO TÍ KỌJÁ AAYÉ Ẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, March 16, 2020

AYÉ Ò! PETER FATOMILỌLA, AGBA Ọ̀JẸ̀ NIDI IṢẸ́ TÍÁTÀ SỌRỌ ÀBÙKÙ SI ALÁÀFIN Ọ̀YỌ́, O LOO TÍ KỌJÁ AAYÉ Ẹ


Ogbontarigi olukọ ede ati Aṣa Yoruba, Peter Fatomilọla ti sọ pe, bi Alaafin ilu Ọyọ, Ọba Lamidi Adeyẹmi Kẹta, ṣe dá si ọrọ awọn lọba-lọba ipinlẹ Ekiti ko bojumu to.

Fatomilọla to tún jẹ́ àgbà ọjẹ nìdí iṣẹ tiata àti onimọ nipa àṣà ati ede Yoruba sọ pe, bi igba ti eeyan tasẹ agẹrẹ ni igbesẹ alaafin náà ri.

"Bi igba ti eniyan lọ sile onile ni. O dabi ki gomina ipinlẹ Ọ̀yọ́ lọ si Ekiti, lọ maa da si ọrọ oṣelu wọn, yoo gba eebu ati abuku bọ ni, tori aja kii roro, ko ṣọ ojule meji."

"To ba jẹ pe Ọọni Ile Ifẹ lo gbe iru igbesẹ yii, o dara, nitori pe, oun ni olori ade gbogbo ilẹ Yoruba. Oun nikan lo le dan iru rẹ wo. Igbesẹ ti Alaafin gbe yii, o fẹ tun fi da ogun silẹ laarin awọn lọba-lọba Ekiti ni. Ọdun mẹrindinlogun si ni Ọ̀yọ́ fi ba Ekiti jagun."

Nigba ti a beere taa ba wo ọjọ ori, ṣe alaafin ko lẹtọ lati dasi ọrọ naa, Fatomilọla sọ pe, agba ko kan ọrọ yii, kii si se ti ọjọ ori pẹlu. Ti eniyan ba dagba, o yẹ ko mọ nkan to tọ lati se.

O ni ki Fayemi paapa ma danwo lati rọ awọn ọba loye tori awọn ọba naa lẹtọ lati yari fun gomina to ba gbe ọba ti ko tọna wa fun wọn, bẹẹ si ni kii ṣe gbogbo ọba Ekiti lo wọ igbimọ Pelupelu .

"Awọn ọba to ba tọ si bi i Ẹlẹkọle ti Ikọle, Ajero ti Ijero, Alara ti Ilara, Ewi ti Ado ati awọn miran nikan lo lẹtọ si igbimọ naa lati lọ si ipade. Wọn si tun lẹtọọ lati ba Fayemi wi, ki wọn si tun gba a nimọran to ba tasẹ agẹrẹ."

"Oṣelu lo ti ba nkan jẹ, oun naa lo si mu ki iru Alaafin Ọyọ maa dasi nkan to n lọ l'Ekiti. Kii ṣe pe gbogbo Ekiti ko ni baba nile, wọn wa n wa baba lọ sode."

A ti sọ fun yin saaju pe ọsẹ to kọja ni Alaafin kọ lẹta kan si Gomina Fayẹmi, lẹyin ti Fayẹmi kede pe, oun yoo rọ awọn ọba kan l'oye l'Ekiti nitori pe wọn n fapajanu lori ẹni to fi jẹ alaga awọn ọba ipinlẹ naa.

Isẹlẹ yii si lo ti n fa awuye-wuye laarin awọn ọmọ ilẹ Yoruba. Ṣugbọn lọjọ aiku ni Fayẹmi lọ si ọdọ Alaafin lati ni ijiroro pẹlu rẹ, eyi to ṣeeṣe ko jẹ lori ọrọ lẹta naa.

Lati: BBC

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI