Ìkéde fún àgbájọwọ́ àwọn ọmọ káàrọ́ọ̀ Ajìíre bí? fún ṣíṣe ayẹyẹ ọjọ́ èdè abínibí.
Ẹgbẹ́ Yoruba Lagba Culture Initiative ńpè yín láti fọwọ́sọwọ́pọ̀ pẹ̀lú wa lati jọjọ ṣe ayẹyẹ ọjọ́ Àyájọ́ èdè abínibí ilẹ̀ Yorùbá ní ọjọ́ kerìnlélógún Oṣù Kẹta, ọdún tí a wà yí, ní ìlú Ìbàdàn. Ní Gbọ̀ngàn asòfin Ìpínlẹ̀ Oyo, Ìbàdàn, Ní dédé agogo mẹ́wàá òwúrọ̀.
Iye owó tí a fẹ́ ná fún gbogbo ètò náà bọ́ sí ₦1,600,000. Ètò náà má ṣe àfihàn orósirísi ẹgbẹ́ alásà àti Ìṣẹ̀ṣe ilẹ̀ Yorùbá. Ó má jẹ́ ọjọ́ ìdárayá àti ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún gbogbo àwọn tí ó bá wá lọ́jọ́ náà.
Ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ fi ọwọsọwọ́pọ̀ pẹ̀lú wa lè nà ọwọ síwa sì àpò ìfowópamọ́ yìí:
Orúkọ: Lawal Kazeem
Banki: POLARIS Bank (former skye Bank)
Akanti: 1018721256
Ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ : 08068465854
Owó ṣe pàtàkì o, àmọ́ Owó kọ́ nìkan lẹ lè fi fọwọ́sọwọ́pọ̀ pẹ̀lú wa, ìfarahàn yín l'ọ́jọ́ ayẹyẹ na àti àwọn tí ẹ bá lè pè wá sí ayẹyẹ náà je ìbánisepọ̀ tí á dùn mọ́ wa nínú gidigidi.
A dúpẹ́ lọ́wọ́ yín gidigidi fún àtìlẹ́yìn yín.
Àwọn tó nilé ayé á fún wa ṣe,
Elédùmarè a fún wa ṣe.
Yorùbá, ọmọ aládé niwá.
Adé Orí wa, kò ní sí láyé láyé.
No comments:
Post a Comment