Ilé ẹjọ gíga kan ní ilú Abuja ti dájọ ikú fún
obinrin kan to ti ọkọ rẹ bo lati ilé ori okè to si kú.
Lónìí ọjọ jimọ ni adajọ AT Badamosi dájọ fún ẹni
ọmọ ọdun mọ́kanlélọ́gbọ̀n kan Rashida Saidu nitori pe o jẹbi ẹsùn ìpànìyàn ikú
ọkọ rẹ Adamu Ali nitori pe o ti wọ́n láti ori ilé alaja.
Ogunjọ oṣù keji ọdun 2019 ni iṣẹ̀lẹ̀ náà ti
ṣẹ̀lẹ̀ ni àgbègbè Dorayi ni Kano lásìkò ti òun ati ọkọ rẹ̀ ni gbolohun asọ.
Ìjà bẹ́ silẹ̀ nígbà to gbọ́ pe ọkọ oun ń bá
obinrin ti o fẹ̀sun kan pe o jẹ ọ̀rẹ́binrin rẹ̀ sọ̀rọ̀ lóri foonu
Lẹ́yin to ti jabọ lo ti wà ni ẹsẹ̀ kan aye ẹsẹ̀
kan ọ̀run, eyi si lo bá kú.
Gẹ́gẹ́ ìròyìn ṣe sọ, ọmọ meji ni Rashida bi òun
lo ni ilé ti wọ́n gbé, bákan náà oun ni ìyàwò ẹlẹ́kiji Adamu lásìkò ìṣẹ̀lẹ̀
náà.
Kí wọ́n to ṣe igbéyawò, wọ́n pàdé ni Federal
College of Technology ni Kano nibi ti wọ́n ti pada fẹ́ àra wọ́n.
Sáájú kii Rashida to pa ọkọ rẹ̀ ni o ti sọ fun
ọ̀rẹ rẹ̀ ti wọ́n jọ n gbe pe ki o dúró náà sùgbọ̀n ko gbọ́ osi gba ilé lọ ti
iṣẹ̀lẹ̀ aburu náà fi ṣẹlẹ̀.
Lati BBC
No comments:
Post a Comment