Pẹ̀lú bí nǹkan ṣe ń lọ n'ilu Iléṣà, ipinlẹ Ọṣun
lásìkò yìí, afaimọ kò má jẹ́ pé ogún abẹle tí agbára kò ní í ká yóò bẹ silẹ
lójijì, pàápàá b'ijọba ipinlẹ náà kò bá tètè dá sí í.
Ko si nnkan méjì tí wọn lo ń dá wàhálà n'ilu Iléṣà
lásìkò yìí, bí kò ṣe b'awọn aráàlú ṣe f'ẹsun ìwà aibikita àti imọtara-ẹni-nikan
kan Ọba Gabriel Adekunle Aromọlaran, Ọwá tilu Ọbọkun Adimula, tí wọn sì l'oun
lo ń mú ifasẹyin b'awọn ìlú tó wà lábẹ́ rẹ.
Gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbọ, wọn ní Ọba Adekunle Aromọlaran
tó jẹ́ olórí gbogbo àwọn ọba n'Ileṣa kò faaye kankan silẹ f'awọn ileeṣẹ ńlá-ńlá
láti wọlé, kò dá tí wọn ní ọ̀nà tó fi ń gba owó abẹtẹlẹ lasiko yìí tí kọjá
afẹnusọ.
AWIKONKO gbọ pé Ọba Aromọlaran lo fi owó lè gbajumọ
ojiṣẹ Ọlọ́run nnì, Pasitọ Adejare Adeboye to jẹ́ alakoso ṣọọṣi Ridiimu, ìyẹn
The Redeemed Christian Church of God láti kọ fasiti rẹ silu l'ọdun 2005.
Àwọn tó f'iṣẹlẹ náà tó AWIKONKO létí jẹ́ kó yẹ wá pé
ọgọrun miliọnu {100,000,000} náírà ni Ọba Aromọlaran kejì ń béèrè lọ́wọ́ Pasitọ
Adeboye láti fi gba àṣẹ fún kíkọ fasiti Redeemers, èyí ni wọn lo ó dà á tí wọn
ṣe lọọ fibinu kọ fasiti náà silu Ẹdẹ, lopopona Gbọngan sì Oṣogbo.
Yàtọ̀ sí èyí, a gbọ pé ọpọ ìgbà t'awọn oludasile
ileeṣẹ ńlá-ńlá bá ti wá ní Ọwá tilu Ọbọkun máa ń fi owó obitibiti owó lè wọn
dànù, èyí tí wọ́n lo ń fà ijakulẹ àti ifasẹyin b'awọn agbegbe tó wà n'ibẹ.
Wọn l'awọn aráàlú, tó fi mọ àwọn ọba alaye tó wà
lábẹ́ Ọwá ni wọn ti pé Kabiyesi sì àkíyèsí, tí wọn sì ti bẹ ẹ láti gba
idagbasoke n'ilu, ṣùgbọ́n tí wọn ní kó gbọ, kò dá tí wọn ní ọpọ̀ ìgbà ni Gomina
àná nipinlẹ náà, Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla tí dá sí í.
Gbogbo akitiyan Gomina Arẹgbẹṣọla nígbà náà pẹ̀lú
àwọn igbimọ tó gbé kalẹ láti gbé ọ̀rọ̀ náà yẹwo lo ja si pàbó títí tó fi kúrò
nibẹ.
N'igba to ń b'awọn akọroyin sọ̀rọ̀ lórí iṣẹlẹ náà ni
Ààfin rẹ laipẹ yìí, Ọba Oyekanmi Ogendengbe tó jẹ́ Ọbanla tilu Ìjẹ̀ṣà sọ pé
ibanujẹ lo máa ń jẹ f'oun at'awọn yòókù tó wà lábẹ́ Ọba Aromọlaran wí pé ìlú tó
yẹ kó máa lewaju l'awọn èèyàn wa ń fi ọwọ rọ tí sẹ́yìn.
Ọba Ogedengbe tó tún jẹ́ igbakeji olórí ọba n'ilu
Iléṣà sọ pé Ọba Aromọlaran tí dalẹ àwọn alalẹ àtàwọn òrìṣà ilẹ̀, èyí tó lo ń jẹ
kò ṣiwa hu gidigidi.
Ọbanla ni àwọn ìwà tí Ọwá ń hù fi hàn pé ìgbéraga to
kọjá sisọ wá, tí kò sì ṣeni tí kò lè sọ̀rọ̀ burúkú sì, àti pé ọpọ ìgbà lo tí
tàpá sì àṣẹ àti òfin ìjọba.
Baba àgbà náà wá ń rawọ ẹ̀bẹ̀ s'ijọba apapọ àti
ìjọba Ìpínlẹ̀ Ọṣun lábẹ́ Gomina Oyetọla wí pé kí wọn tètè b'awọ̀n kilọ fún Ọba
Aromọlaran láti jẹ ki ìdàgbàsókè wọlé wá fún wọn.
Síwájú sí í lo sọ pé bí wọn kò ba dá Kabiyesi náà
lọ́wọ́ agbára tó ń lo lè àwọn lórí kọ, ìpalára ńlá tó ju ti àtẹ̀yìnwá lọ ní yóò
má a b'awọ̀n lopọ, bẹ́ẹ̀ lo ni ìwà aṣiwaju lo yẹ kí Ọba alaye náà máa hu
láwùjọ.
Nínú ọ̀rọ̀ tiẹ̀, Ọwá tilu Ọbọkun tí Alagba T. A
Ọlatunbọsun gba ẹnu rẹ sọ̀rọ̀ sọ pé alatẹnujẹ l'awọn tó ń ṣagbatẹru àwọn ọ̀rọ̀
tí kò lẹsẹ nilẹ naa, o ni ki wọn mu awọn ẹri aridaju wọn sita f'awọn eeyan lati mọ.
No comments:
Post a Comment