Ko si ọrọ meji
to n ja rain-rain nilẹ kaakiri orilẹ-ede Naijiria
l’asiko yii bi ko ṣe ti ọdọmọkunrin
kan ti wọn lo o lu awọn eeyan to to ẹgbẹrun mẹwaa ni jibiti owo ti ko din
ni biliọnu mẹsan an (N9b) naira, ti wọn si
lo n gbero lati na papa bora pẹlu owo olowo.
Ọsẹ to kọja yii
la gbọ pe aṣiri ọdọmọkunrin
naa ti wọn pe orukọ rẹ ni Nwabuba Victor Ifeanyi, ti wọn ni ẹka ikẹkọọ Chemistry lo wa
ni fasiti ti wọn ti n kọ nipa iṣẹ agbẹ ati ọgbin,
iyẹn FUNAAB n’ilu Abẹokuta,
ati pe ipele to gbẹyin, iyẹn 400level lo wa tu s’awọn eeyan l’ọwọ l’asiko ti wọn
lo n di ẹru rẹ lati salọ s’ilu Dubai ni orilẹ-ede Egypt.
Gẹgẹ
bi a ṣe gbọ, wọn ni ọdun to kọja ni Victor bẹrẹ ifowo-dokoowo ori ayelujara ti wọn
n pe ni Forex Trading, ti wọn si l’awọn
to lowo lowo daadaa ni wọn n fowo si i lati d’okoowo pẹlu e.
A gbọ
pe ida ogun (20%) ni Victor maa n fun
awọn to ba k’owo si ileese rẹ lori ayelujara to pe ni Vickson Enterprise l’eyin ọsẹ meji, ti inu wọn yoo si dun un. Eyi
gan an ni wọn lo o jẹ k’awọn to mo eto yii bẹrẹ si i pe awọn ọrẹ rẹ at’awọn ebi wọn lati fi
owo wọn si i, k’awọn naa le jẹ ninu anfaani naa.
Wọn ni
awọn bi ojogbọn, oluko, akekoo at’awọn eeyan n’ile eko fasiti FUNAAB ati
jakejado ni wọn ko owo si i, ti wọn si n gba owo naa bo ṣe ye, ti a si gbọ pe awọn
ti ko din ni egberun mewaa eeyan ni wọn n f’owo wọn d’okoowo pẹlu Victor.
Ṣe ni wọn
ni nnkan ko lo gẹgẹ bo ṣe ye ko lo ni nnkan bi ọsẹ meta s’eyin, ti wọn si l’awọn
to n f’owo d’okoowo ko ri owo gba mo, ti wọn si l’awọn eeyan bẹrẹ si i beere l’ọwọ
ara wọn pe ki lo le sele, sugbọn ti wọn ko r’ẹni da wọn
lohun.
Gbogbọ
igba la gbọ pe wọn maa n pe Victor lori foonu lati beere idi ti ko fi san owo
olowo, ti a si tun gbọ pe ṣe l’awọn ti wọn gbiyanju lati fi opin si okoowo naa
ko ri owo wọn gba pada.
Wọn ni
n’igba t’awọn eeyan ko gburo Victor lo jẹ ki wọn gbera lọ ọ ba a
n’ile ẹ l’ọjọ Wesidee ọsẹ to kọja yii, ti wọn si
ri i pe o ti di gbọgbọ ẹru rẹ lati na papa bora, eyi lo mu ki wọn bẹrẹ si i f’inibu
luu, ti wọn si wo o lo teṣan ọlọpaa to
wa ni Eleweran lati fi to ọga ọlọpaa
leti.
AWIKONKO
gbọ pe Victor ti pari idanwo aṣekagba rẹ, ti wọn si lo n
duro lati pari idanrawo, iyẹn Project ẹ, ṣugbọn ti wọn ni gbọgbọ erongba rẹ ni lati fi owo rin in, ko
le ri owo olowo gbe salọ lo n wa.
Gbogbo
akitiyan lati ba Abimbọla Oyeyẹmi sọrọ lori
iṣẹlẹ naa lo ja si pabo titi d’asiko ta a ṣ’akojọpọ
iroyin yii tan.
No comments:
Post a Comment