UDOH! ỌMỌ NAIJIRIA, AGBABỌỌLU AKỌKỌ TI YOO KO AARUN CORONAVIRUS - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, February 29, 2020

UDOH! ỌMỌ NAIJIRIA, AGBABỌỌLU AKỌKỌ TI YOO KO AARUN CORONAVIRUS

Bi ẹ ṣe n ka iroyin yii, awuyewuye to tẹ wa l'ọwọ bayii ni pe ọmọ orilẹ-ede Naijiria to n gba bọọlu lorilẹ-ede Italy, iyẹn King Paul Akpan Udoh la gbọ pe oun naa ti fara gba ninu aarun aṣekupani Coronavirus to n tan kaakiri agbaye lasiko yii.

King Paul ti wọn lo o ṣẹṣẹ pari iduna-dura pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu Pianese ninu idije Italian Serie C la gbọ pe oun ni agbabọọlu akọkọ ti yoo kọkọ ni aarun naa lara. Ọjọbọ ti i ṣe Tọside ijẹta la gbọ pe wọn ṣayẹwo fun un, ti wọn si ri i pe aarun naa ti wa lara rẹ.

Ẹgbẹ agbabọọlu Reggiana ni King Paul,ọmọdun mejilelgoun naa ti bẹrẹ ko to o di pe o darapọ mọ Juventus l'ọdun 2011, n'ibi ti wọn ti pada fi gba paarọ fun ọdun kan ni Virtus Lanciano ti ẹka idije Serie B l'ọdun 2016.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI