O ti ṣe díẹ̀ báyìí tí awuyewuye náà tí ń lọ káàkiri igboro nípa gbajúmọ olorin t'ọpọ àwọn èèyàn gbagbọ wí pé ó fẹ́ràn láti máa kọ ikọkukọ, Janet Ajilore Iyùn, ìyẹn Saint Janet.
Kò sí ọ̀rọ̀ awuyewuye tó ń lọ nípa Saint Janet lásìkò yìí, bí kò ṣe b'awọn kan ṣe ń sọ pé ojú tí ń dùn ún, tó sì mú kó máa lo ìgò dúdú.
A gbọ pé Saint Janet kò lè lọọ kọrin f'áwọn olólùfẹ́ ẹ lásìkò yìí mọ lai lo ìgò dúdú soju, èyí tí wọn loo fà á t'awọn kan fi ń sọ pé ojú tí ń dùn ún, kò sì fẹ́ k'awọn èèyàn mọ bó ṣe ń lọ nípa rẹ.
Ọmọ bíbí Ìpínlẹ̀ Ọṣun náà l'awọn kan ń sọ pé ó ṣeé ṣe kó jẹ pe irun t'awọn obìnrin máa ń lé mọ irun ojú wọn lo ṣàkóbá fún ojú to ń dùn Saint Janet.
Ṣùgbọ́n lai pẹ yìí ni obìnrin náà sọ̀rọ̀ lórí redio kan n'ilu Abẹ́òkúta, nibẹ lo sì ti jẹ́ k'awọn tó ń gbé awuyewuye náà káàkiri wí pé kò sí nnkan tó ṣe ojú òun, bẹ́ẹ̀ ni ojú kò dùn òun.
O tún fi àdúrà kún ọ̀rọ̀ rẹ wí pé "Ọlọ́run kò ní jẹ́ kí n rí nnkan ti yoo jẹ ki ojú dùn mi."
No comments:
Post a Comment