L'oni-in ọjọ Isinmi, ìyẹn Sannde àkọ́kọ́ ninu oṣù keji yii ni gbajumọ Pasitọ nni, Pasitọ Enoch Adejare Adeboye to jẹ alakooso agba ìjọ Ridiimu s'iwaju àwọn ọmọ ìjọ Ridiimu lati ṣe iwọde láti tako ifẹmiṣofo to n lọ kaakiri orilẹ-ede yii, paapaa lat'ọwọ àwọn alakatakiti Boko Haram.
Lati olu ile ijọsin Ridiimu to wa l'agbegbe Ebute Mẹta l'Ekoo ni Pasitọ Adeboye ti ṣ'iwaju àwọn ọmọ ìjọ rẹ lati rin de itẹ-oku Atan to wa ni Yaba l'Ekoo, ki wọn too pada.
Ninu ọrọ rẹ, Pasitọ Adeboye ni, ifẹmiṣofo to n lọ kaakiri orilẹ-ede yii ti wa kọjá sisọ. O ni, ẹmi kirisitẹẹni ati musulumi ṣe pataki pupọ si Ọlọ́run, ti ko si yẹ ko maa sọnù bẹẹ. O gbadura pe, ki alaafia jọba pada l'órílẹ̀-èdè yii.
Bi ẹ ko ba gbagbe, nitori ifẹmiṣofo to l'agbara ati ijinigbe to n ṣẹlẹ̀ l'órílẹ̀-èdè yii ni ẹgbẹ́ àwọn kirisitẹẹni l'órílẹ̀-èdè yii, Christian Association of Nigeria (CAN) ti kede adura ati aawẹ fun gbogbo kirisitẹẹni orílẹ̀-èdè yii, ti wọn si tun pa gbogbo kirisitẹẹni l'aṣẹ lati ṣe iwọde l'ori ifẹmiṣofo naa jakejado orílẹ̀-èdè yii, ìyẹn bi wọn ba ti pari isin ọjọ́ Isinmi oni.
No comments:
Post a Comment