OYÈ OLUBADAN KÒ SÍ FÚN TÍTA Ó - LEKAN BALOGUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, February 18, 2020

OYÈ OLUBADAN KÒ SÍ FÚN TÍTA Ó - LEKAN BALOGUN


Otun ti ilu Ibadan, Lekan Balogun ti ni oye ni ilu Ibadan kii ṣe fun tita bi Olubadan ṣe n ta oye fun awọn eniyan.

Balogun ni lati ogoji ọdun sẹyin ti oun ti jẹ ọkan gboogi fun idile ọba ni ko ti í si ẹni to n ta oye ni ilu Ibadan.

O ni ẹgbẹrun meji naira si ẹgbẹrun marun naira ni awọn ti wọn ba fi jẹ oye ni ilu Ibadan ma n san, amọ awọn n gbọ pe Olubadan n ta oye fun awọn eniyan ni ọgbọn miliọnu naira.

Otun ni ohun ti wọn ma n ṣe ni Ibadan ni wi pe, wọn ma n fi oye fun awọn ti wọn ba ni orukọ rere ni awujọ, bi wọn ko tilẹ ni owo lọwọ.

Amọ, O ni ohun ti oun gbọ ni wi pe ẹni ti o ba ni owo julọ ni Olubadan n fun ni oye, bi ko tilẹ ni orukọ rere.

Lori ẹsun wi pe wọn fẹ yọ ọba Olubadan ni ipo, Otun ti ilu Ibadan ni awọn ko sọ wi pe awọn fẹ yọ Olubadan.

Ati wi pe ẹṣẹ si awọn afọbajẹ, iyẹn Balogun ati olori ile Olubadan ni ilu Ibadan ko lee sọ wi pe ki wọn yọ ọba bi o tilẹ jẹ pe wọn ni aṣẹ lati yọ Olubadan ni ipo.

O fi kun un wi pe ẹṣẹ si ilu ni awọn fi le yọ Olubadan ni ipo, ati wi pe tita oye ilu Ibadan ja si ẹṣẹ si ilu, amọ awọn ko ni i lọkan lati yọ Olubadan nipo.

Balogun fi kun un wi pe yiyọ Olubadan ni ipo lee ba ilu Ibadan jẹ, eleyii ti awọn ko fẹ ko ṣẹlẹ.

Amọ gbogbo igbiyanju wa lati jẹ ki Olubadan fi ero rẹ lede lori ẹsun ti wọn fi kan an naa lo ja si pabo. Agbẹnusọ fun Olubadan, Adeola Oloko ko gbe ẹrọ ibanisọrọ rẹ, bakan naa ni oluwoye igbesẹ, Yanju Adegboyega naa ko gbe ẹrọ ilewọ rẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI