Ọpọ awọn to gbọ nipa iroyin iku
baale ile kan ti a ko ti i mọ orukọ rẹ titi ta a fi kọ iroyin yii tan, ẹni ti
wọn lo o ku s'ori ọdọmọbinrin aṣẹwo kan ni wọn n sọ pe ohun to mọ ọn jẹ naa lo
ran an lọ s'ọrun apandodo, ati pe ibi to gba wa sile aye naa lo tun gba pada.
Gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ ṣe
sọ, wọn ni baale ile naa ni aisan kan lara, ti wọn si lojoojumọ lo maa n lo
oogun, ati pe awọn dọkitọ ti sọ fun un pe ko rọra maa ṣiṣẹ agbara.
Ile igbafẹ kan ti a f’orukọ bo
l’aṣiri to wa n’ipinlẹ Akwa-Ibom la gbọ pe iṣẹlẹ naa ti waye laaarọ onii. Wọn
ni ọrẹ gendebinrin alaṣẹwo yii ti wọn pe orukọ ẹ ni Precious lo jẹ k’oun ati
baal ile naa mọ ara wọn.
Ko pẹ ti wọn sọ pe Precious ati
baale ile naa ni ibalopọ gbigbona tan ni wọn gbagbe sun lọ, ko si pẹ ti wọn ni
Precioius fi dide lati wa onibara mi in lọ, ti wọn si lo o ji ọkunrin lati gba
owo iṣẹ to ṣe, ṣugbọn ti wọn ni ko ji i.
L’oju ẹsẹ ni wọn lo o ti pariwo
sita pe k’awọn eeyan to wa ni otẹẹli naa gba oun nitori pe ẹni t’awọn jọ ni
ibalopọ ti dagbere f’aye. N’igba ti wọn fi maa wo baagi ọkunrin naa, awọn oogun
oriṣiriṣi to fi n t’ọju ara rẹ la gbọ pe wọn ba n’ibẹ.
No comments:
Post a Comment