Ogbologbo aṣẹwo ni ọdọmọbinrin ti ẹ n wo yii tẹlẹ, ko sẹni ti ko mọ-ọn laarin asiko to fi yan iṣẹ naa laayo ko to o di pe o fi silẹ patapata. Bo tilẹ jẹ pe a ko ti i mọ orukọ rẹ, ṣugbọn orukọ t'awọn eeyan fun un ni Judith.
Judith lo ṣalaye idi to ṣe fi iṣẹ aṣẹwo silẹ patapata, to si l'oun ko le gbagbe ọjọ naa titi lai, tori pe ọjọ buruku eṣu gbomimu lọjọ naa jẹ.
O ni lara ọjọ t'oun yoo maa fi waasu lojoojumọ lọjọ ti baba oun jẹ onibara oun n'ile aṣẹwo t'oun ti n ṣiṣẹ, to si jẹ pe ṣe l'oun na papa bora l'ọjọ naa.
Judith ni ṣe l'awọn n ja si onibara l'ọjọ naa ko to o di pe baba agba kan de pẹlu fila lori, t'oun ko si ri oju ẹni naa tori pe ilẹ ti ṣu.
O l'awọn ti duna-dura, ko to o di pe awọn gba yara t'awọn yoo ti kona funra labẹ lọ
Ọmọbinrin yii sọ pe b'awọn ṣe wọle sinu yara naa l'oun ti sare bọ sori bẹẹdi, t'oun si ti n bọ aṣọ oun. O ni b'oun ṣe bọ aṣọ tan, to ku k'oun bọ pata, nitori pe oun ti n reti lati gba kinni abẹ baba naa sara, k'oun si tete wa onibara mi-in lọ ni baba naa ṣi fila lori, tẹni naa si di baba to bi oun l'ọmọ.
Ẹru lo sọ pe o ba oun t'oun si fi itiju sa jade l'ọjọ, ti ko si sẹni to mọ b'oun ṣe rin in.
Ọdun karun un re e to sọ pe iṣẹlẹ naa waye, ṣugbọn to l'oun dupẹpe latigba naa ni igbesi aye oun ti yi pada. O tun jẹ ko ye awọn eeyan wi pe oun ati baba oun ko gbe ọrọ naa sọ lẹnu tabi ba mọlẹbi kankan sọ ọ titi di asiko yii.
No comments:
Post a Comment