OPOPONA IJẸBU-ODE-ẸPẸ: ỌDUN KAN GBAKO L'AWỌN AGBAṢẸṢE YOO LO - DAPỌ ABIỌDUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, February 27, 2020

OPOPONA IJẸBU-ODE-ẸPẸ: ỌDUN KAN GBAKO L'AWỌN AGBAṢẸṢE YOO LO - DAPỌ ABIỌDUN

L'Ọjọru ti i ṣe Wẹside ana n'ijọba ipinlẹ Ogun labẹ Gomina Dapọ Abiọdun lọ ọ fi ipilẹ opopona Ijẹbu-Ode si Ẹpẹ lelẹ, t'awọn agbaṣẹṣe si ti bẹrẹ iṣẹ akanṣẹ naa ni pẹrẹu bayii.

N'ibẹ ni Gomina Abiọdun ti f'idi rẹ mulẹ wi pe ko ni i le ni ọdun kan t'awọn agbaṣẹṣe naa yoo lo lati fi pari iṣẹ opopona oni kilomita mẹrinla (14-km) naa, lati tete jẹ ki awọn eeyan bẹrẹ si i jẹ igbadun mudun-mudun eto oṣelu awaarawa.

F'awọn to ba mọ bi nnkan ṣe n lọ lasiko yii, wọn a mọ pe sunkẹrẹ-fakẹrẹ igboke-gbodo ti kọja afẹnusọ lopopona ilu Ibadan si Eko, to si mu k'awọn arin-rin-ajo maa lo ọpọ wakati ki wọn to o de ibi ti wọn lọ.

Agbegbe Ikoto n'ijọba ibilẹ Odogbolu, Ijẹbu-Ode ni opopona yoo ti bẹrẹ, ti yoo si pari si ibi ti ilu Eko pari si, iyẹn ni Ẹpẹ lati le jẹ ki eto ọrọ aje tubọ gun oke si.

Ileeṣẹ kan ti wọn pe ni Craneburg Construction la gbọ pe wọn gbe iṣẹ naa fun, ti a si gbọ pe wọn yoo ṣe agbegbe kan ti wọn yoo ti maa gba owo, iyẹn toll ti wọn yoo maa fi mojuto opopona naa loore-koore.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI