Ijọba ipinlẹ Ogun ti ba gbogbo awọn ọlọja ti ọn padanu dukia at'awọn ọja wọn s'inu ijamba to ṣẹlẹ laipẹ yii kẹdun, to si ṣeleri fun wọn pe ijọba yoo ran wọn lọwọ bi asiko ba to.
N'igba to n gba ẹnu Gomina ipinlẹ naa, Ọmọọba Dapọ ABiọdun sọrọ, igbakeji rẹ, Onimọ-ẹrọ Nọimọt Salakọ-Oyedele n'ibi abẹwo to ṣe lọ s'ibi ijamba inaa to wa ni ọja Origbẹgi ni oju irin reluwa to wa ni Lafẹnwa n'iluu Abẹokuta, o sọ pe ẹdun ọkan n'iṣẹlẹ naa jẹ f'oun.
Igbakeji Gomina yii sọ pe igbesẹ ti yoo jẹ k'awọn ọlọja naa tete pada s'idi ọja wọn n'ijọba yoo gbe e, ti onikaluku wọn yoo si rẹrin nitori pe alaafia araalu lo jẹ ijọba yii l'ogun pupọ.
N'igba to fi awọn iṣẹlẹ ijamba ina to n waye kaakiri lasiko yii ṣe apẹẹrẹ, O rọ gbogbo awọn araalu wi pe ki wọn ṣọra f'awọn nnkan to le fa ijamba ina to n fi dukia ṣofo danu l'asiko yii, nitori pe ibanujẹ lo maa n jẹ lati padanu dukia tabi ẹmi awọn eeyan.
No comments:
Post a Comment