Titi di asiko ti a fi kọ iroyin yii tan n'iku ọkan lara awọn ọga ọlọpaa to wa l'ẹka ọlọpaa kogberegbe, iyẹn FSARS n'ilu Ikẹja, ipinlẹ Eko ṣi n jẹ iyalẹnu pupọ, paapaa f'awọn to wa n'ibẹ lasiko iṣẹlẹ naa.
Ọjọ Ẹti ti i ṣe Fraide ọsẹ to kọja yii la gbọ pe ọga ọlọpaa (Senior Police Officer) naa, ASP Christopher Akpan yọ ṣubu ninu ọfiisi rẹ, to si ko awọn eeyan sinu ibẹrubojo.
AWIKONKO gbọ pe ibi iṣẹ kan ni Akpan at'awọn ọlọpaa abẹ ẹ meloo kan ti n bọ l'ọjọ naa, igba ti wọn de ni wọn sọ pe Akpan lọ si baluwẹ lati wẹ idọti ara rẹ danu. Wọn ni bo ṣe n jade jurọ ninu baluwẹ to wa ninu ọfiisi rẹ ni ẹsẹ rẹ yọ, to si ṣubu lulẹ.
Oju lasan ni wọn l'awọn ọlọpaa to wa n'itosi kọkọ pe e, to mu ki wọn sare gbe Akpan, ọmọ bibi ilu Akwa-Ibom lọ si ọsibitu to wa n'itosi lati doola ẹmi rẹ, ṣugbọn ti wọn ni oju ọna lo ti dakẹ.
Ṣe ni omije n pe omije ran niṣẹ nigba ti wọn l'awọn dokita sọ pe oku ni wọn gbe f'awọn, ti wọn si gbe e wọ mọṣuari lati ṣayẹwo iku to pa a, iyẹn autopsy.
Baraaki Ọkọta n'ilu Eko la gbọ pe Akpan gbe pẹlu iyawo at'awọn ọmọ rẹ, ti wọn si ni ọlọpaa to mọ iṣẹ rẹ d'oju aami ni.
Ohun ti ọpọ awọn eeyan n sọ ni pe ko daju wi pe iku Akpan jẹ oju lasan, ti wọn si lo ṣeẹ ṣe ko lọwọ aye ninu.
No comments:
Post a Comment