Bi ẹ ṣe n ka iroyin yii, Gomina
ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun ti sọ pe k’awọn ọba marundinlọgọrin (75) ti
Gomina anaa n’ipinlẹ naa, iyẹn Ibikunle Amosun lọọ gbe ade wọn pamọ, tori pe
ipo ọba ko tọ si eyikeyi ninu wọn.
F’awọn to ba mọ bi nnkan ṣe n
lọ si i, bo ṣe ku diẹ ki iṣakoso Sẹnetọ Ibikunle Amosun d’opin gẹgẹ bi i Gomina
lo sọ awọn baalẹ ti ko din l’aadọta at’awọn oloye kọọkan di ọba ojiji, to si ni
ki gbogbo wọn lọ maa palẹmọ fun iwuye wọn, ṣugbọn ti wọn ko ri i ṣe n’igba naa.
Ni bayii, lẹyin igbimọ ti Gomina Abiọdun gbe kalẹ lati ṣe iwadii b’awọn baalẹ naa ṣe di ọba ojiji, ni olori ọba ilẹ Yewa lapapọ, iyẹn Olu-Ilaro, Ọba Kẹhinde Olugbenle sọ pe ọna ti ko b’ofin mu ni wọn fi sọ awọn eeyan naa di ọba, ati pe pupọ wọn ni ko lẹtọ si ipo naa.
Eyi lo fa a ti Gomina Abiọdun fi paṣẹ pe k’awọn to
ti n pe ara wọn l’ọba lọọ gbe ade wọn pamọ, ati pe k’awọn baalẹ ti wọn di ọba
ojiji yii naa pada si ipo ti wọn wa tẹlẹ.
No comments:
Post a Comment