Awọn ọlọpaa l'orilẹ-ede Rwanda sọ pe akọrin kan t'awọn mu lọsẹ to kọja nigba ti o fẹ sa kuro nilu ti pa ara rẹ ni atimọle.
Gẹgẹ bi ohun ti wọn sọ, Kizito Mihigo n gbiyanju lati lọ darapọ mọ awọn ajijagbara kan ni orileede Burundi.
Akọrin naa ti lo ọdun mẹta lẹwọn latara bi ijọba ṣe fẹsun kan pe o n gbimọran lati ditẹ gbajọba.
Amọ ṣa, awọn ajafẹtọmọniyan lẹyin odi ti fi ọwọ rọ alaye awọn ọlọpaa yi ṣi ẹgbẹ kan.
Wọn ni Kizito ko ni erongba lati darapọ mọ awọn ajijagbara kankan bi kii ṣe pe o fẹ lọ si orileede Belgium nibi to ti fi igba kan gbe ri.
Bẹẹ ni wọn lawọn ko gbagbọ pe o gbẹmi ara rẹ lahamọ ṣugbọn wọn ro pe awọn ọlọpaa pa ni.
Ohun to da wahala silẹ fun Kizito ni orin rẹ to n kọ.
Ninu ọkan lara orin to fi sita, o sọ pe o yẹ ki ijọba ranti gbogbo awọn to ku ninu iṣekupani lasiko ogun to waye ni Rwanda lọdun 1994 yala wọn jẹ ẹya Hutu tabi Tutsi.
Awọn alaṣẹ lawọn ri ipe rẹ ninu orin naa gẹgẹ bi ọna lati tako ohun ti ijọba sọ pe awọn Tutsi ni wọn ku lasiko ogun to waye nilẹ naa.
Eyi lo mu ki awọn alatako ijọba sọ pe wọn doju le e nitori ọrin to kọ yii.
Ẹwẹ, ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ ni Rwanda lawọn ti bẹrẹ iwaadi lati mọ ohun to ṣokunfa iku Kizito Mihigo.
Agbẹnusọ ileeṣẹ naa, Michelle Umuhoza sọ fun BBC pe wọn ti gbe oku rẹ si ile igbokupamọ si nibi ti wọn yoo ti ṣe ayẹwo ohun to ṣeku pa.
Láti: BBC
No comments:
Post a Comment