Oluwo tilu Iwo, Ọba Abdulrosheed Akanbi ti pariwo sita lori awuyewuye lo n lọ kaakiri igboro lori Ọba to lu l'alubolẹ, wi pe oun ko jẹbi rara.
Ọjọ Ẹti Furaide ana ni Oluwo tilu Iwo lu Ọba Sikirulahi Akinrọpo, Agbowu tilu Ọgbaagba ni ọfiisi igbakeji ọga ọlọpaa orilẹ-ede yii, ẹka tilu Oṣogbo nibi ipade alaaafia ti wọn pe laaarin awọn ilu to wa n'ijọba ibilẹ Iwo, Ayedire ati Ọla-Oluwa, ipinlẹ Ọṣun.
Ko si nnkan meji ti wọn lo ti n fa awuyewuye laaarin Oluwo at'awọn ọba ti ko din ni mẹsan an, ti wọn si ti ko ọrọ naa de iwaju igbakeji ọga ọlọpaa, AIG Bashir Makama.
A gbọ pe ibi ti wọn ti n yanju ọrọ naa ni Oluwo ti sare dide, to si bẹrẹ si i da ẹṣẹ bo Ọba Akinrọpo, titi t'ẹjẹ fi bẹrẹ si i yọ loju ẹ. Loju ẹsẹ ni wọn ti sare gbe Kabiyesi naa lọ si ọsibitu fun itọju.
Ọpọ awọn to ti n sọrọ lori iṣẹlẹ naa ni wọn n bu ẹnu atẹ lu iwa ti Oluwo hu naa, t'awọn kan si n sọ pe o ṣee ṣe ko jẹ pe igbo ati kokeeni to n mu lo n da laaamu.
Ṣugbọn Oluwo funra rẹ ti sọrọ, o ni oun ko jẹbi lori b'oun ṣe ṣina iya fun Ọba Akinrọpo nitori pe ṣe lo kọja aaye ẹ, ti ko si fi ọwọ wọ oun gẹgẹ bi olori awọn ọba lagbegbe naa.
O ni bawo ni iru ọba ti ko to oun ṣe le maa na ọpa s'oun loju, to si jẹ ko di mimọ pe nnkan ti wọn ko ba le ṣe fun Alaaafin Ọyọ ati Ọọni Ile Ifẹ ni wọn ko gbọdọ fi dan oun wo lailai.
O ni bawo ni iru ọba ti ko to oun ṣe le maa na ọpa s'oun loju, to si jẹ ko di mimọ pe nnkan ti wọn ko ba le ṣe fun Alaaafin Ọyọ ati Ọọni Ile Ifẹ ni wọn ko gbọdọ fi dan oun wo lailai.
No comments:
Post a Comment