Ijọba ipinlẹ Ọyọ ti ṣetan lati gunle ipese kaadi
idanimọ fawọn ọlọkada jakejado ipinlẹ naa lọna ati dena iwa ọdaran ati apọju
awọn ọlọkada nipinlẹ naa.
Bakan naa, gomina ipinlẹ Ọyọ, ṣeyi Makinde ti
pàṣẹ pe ki adinku ba igba naira owo ojumọ ti awọn ọlọkada yẹ ko san si ọgọrun
naira.
Kọmiṣanna feto isẹ ode, ipese awọn ohun eelo
amayedẹrun ati igbokegbodo ọkọ nipinlẹ Ọyọ, Raphael Afọnja lo ṣiṣọ loju ọrọ yii
lasiko to n b'awọn akọroyin sọrọ.
Bakan naa lo fi kun un pe gomina Makinde ko fẹ fi kun
ajaga awọn araalu lo ṣe mu adinku ba owo t'awọn ọlọkada yóò maa san, ti yoo si tun
pese kaadi idanimọ fun gbogbo ojulowo ọlọkada pata to n ṣiṣẹ aje nipinlẹ naa.
Gẹgẹ bi Afọnja ti wi, ijọba fẹ gbe igbesẹ naa lati le mọ ojulowo ọlọkada yatọ si awọn to jẹ asawọ laarin wọn nitori gbogbo alaamu
lo da ikun delẹ, a ko mọ eyi ti inu n run ninu wọn.
"Ta ba wo bi ijọba ṣe f'ofin de awọn ọlọkada ati oni kẹkẹ Maruwa nipinlẹ Eko, ọpọ wọn lo ya wa sipinlẹ Ọyọ, a si ti pinnu pe a fi ka ṣ'eto kaadi idanimọ f' awọn ọlọkada naa, ka le mọ ẹni ninu ẹni.
Bakan naa ni kọmiṣanna fun isẹ ode fikun pe ijọba
Ọyọ yoo ṣiṣẹ pọ nifọwọkọwọ pẹlu awọn oṣiṣẹ ajọ ẹṣọ oju popona FRSC pẹlu awọn ẹka
to n pawo wọle labẹle lati ṣe akojọpọ orukọ nipa awọn ọlọkada ero ati aladani,
eyi ti yoo tun wulo fun awọn agbofinro pẹlu.
Afọnja ni "Aṣigbọ kan lo waye laarin wa pẹlu ajọ to n pawo wọle ati ileeṣẹ eto iṣuna, ohun ta gbọ ni pe igba naira lawọn ọlọkada yoo maa san lojumọ, nigba ti gomina Makinde gbọ, ko ba a lara mu rara, to si ni ka mu adinku ba owo ojumọ ti awọn ọlọkada n san lati igba naira si ọgọrun naira."
Kọmiṣanna ni gareeji ọkọ kọọkan ni wọn yoo ti maa
gba owo yii bẹrẹ lati oni, ọjọ Ẹti lọ, to si n rọ awọn ọlọkada lati fọwọsowọpọ
pẹlu ijọba ipinlẹ Ọyọ.
Lati BBC
No comments:
Post a Comment