'Ko le ri bẹẹ, bawo lo ṣe ṣe e' lọrọ kayeefi ti wọn lo n jade lẹnu ọpọ awọn to gbọ pe wọn lu Ọtun-Olubadan tilu Ibadan, Oloye-Agba Lekan Balogun ni jibiti obitibiti owo ti ko din ni ọọdun miliọnu (300,000,000) naira.
Ohun to n jẹ iyalẹnu ni pe ki i ṣe ọjọ kan tabi aarin ọdun kan ni wọn lu Oloye-Agba Lekan Alabi ni jibiti aduru owo naa, bi ko ṣe pe lati nnkan bi ọdun mẹrin sẹyin ni wọn ti n f'ọgbọn gba owo baba naa.
Babatunde Ologunja,
Oluṣọla Ọlaoye Babatunde ati Olufẹmi Lawal l'awọn mẹta ti wọn sọ pe wọn lu ọtun Olubadan naa ni jibiti, ti wọn si ni ko fi bẹẹ si akọsilẹ kankan to f'idi rẹ mulẹ pe wọn jo n duna-dura ohun kan, yatọ si ti banki ti wọn n lo lati fi owo naa ranṣẹ laarin asiko ti wọn fi n gba owo yii.
AWIKONKO gbọ pe ki i ṣe pe iṣẹ lo pa Ọtun-Olubadan at'awọn eeyan yii pọ, to fi di pe wọn n gba owo l'ọwọ rẹ loore-koore, to si jẹ pe iyalẹnu lo jẹ wi pe wọn gba owo naa kọja sisọ.
Awọn mẹtẹẹta re e |
Sẹnetọ to n ṣoju ẹkun Ọyọ Central n'ile igbimọ aṣofin agba laarin ọdun 1999 si ọdun 2003 labẹ asia ẹgbẹ oṣelu AD ni Oloye Lekan Balogun to tun jẹ igbakeji Olubadan ninu igbimọ agbaagba n'ilẹ Ibadan, iyẹn Olubadan-in-Council.
Ki i ṣe pe aṣiri naa dee de tu sita, aburo Oloye Lekan Balogun, iyẹn Sẹnetọ Kọla Balogun to n ṣoju ẹkun Ọyọ South n'ile igbimọ aṣoju-ṣofin la gbọ pe o kọ lẹta ifẹsunkan si ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu, iyẹn EFCC lorilẹ-ede Naijiria wi pe awọn kan lu ẹgbọn oun ni jibiti owo.
Sẹnetọ Kọla Balogun ninu lẹta rẹ naa lo ti sọ pe oju lasan kọ l'awọn eeyan naa fi n gba owo lọwọ ẹgbọn oun lati bi ọdun mẹrin sẹyin, to si ni ṣe ni wọn ra a niye patapata, ti ẹgbọn oun ko si ni i mọ titi yoo fi fun wọn lowo.
O ni apapọ owo ti wọn ti gba lọwọ ẹgbọn oun naa ti n lọ si miliọnu lọna ọọdunrun naira, toun si fẹ ki wọn ba oun ṣeawdi owo naa at'awọn to lu jibiti yii.
Ni kete ti ajọ EFCC ti gba lẹta yii ni wọn ti bẹrẹ iṣẹ iwadii, ti aṣiri awọn mẹta yii si tu, ṣugbọn ti wọn lawọn yooku ti wọn jọ pin owo naa ti na papa bora.
No comments:
Post a Comment