IKUNLẸ ABIYAMỌ O: TIRELA DANGOTE TẸ AWỌN EEYAN PA NI SANGO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, February 15, 2020

IKUNLẸ ABIYAMỌ O: TIRELA DANGOTE TẸ AWỌN EEYAN PA NI SANGO

Ko din ni eeyan meje ti a gbọ pe wọn ti jẹ ipe Ọlọrun bayii sinu ijamba mọto to waye lagbegbe Ilo-Awẹla, Toll Gate ni Sango, ipinlẹ Ogun laarọ oni Satide Abamẹta.
Ni nnkan bi aago mejila ku iṣeju marundinlọgbọn (11:35am) la gbọ pe Tirẹla Dangote tẹ bọọsi Voltswagen LT 35 ati mọto ayọkẹlẹ kan, t'awọn meje si gbabẹ sọda s'ọrun alakeji.
Iwaju ọfiisi awọn ẹṣọ oju popona, iyẹn FRSC la gbọ pe iṣẹlẹ naa ti waye, ti a si gbọ pe loju ẹsẹ l'awọn oṣiṣẹ oju popona yii ti sare debẹ lati doola ẹmi awọn eeyan.

Wọn ni ijanu tirela naa lo da iṣẹ silẹ lori ere, to si mu k'awọn mọto naa ko sabẹ rẹ.

Loju ẹsẹ t'iṣẹlẹ naa ti waye l'awọn tinu n bi ti ju ina si tirela Dangote naa, ti wọn si dana sun un womu-womu. Ọpẹlọpẹ awọn oṣiṣẹ ajọ popona ti agbọ pe wọn gba awakọ Dangote naa silẹ l'ọwọ iku ojiji, n'igba ti wọn ni wọn da igi bo o lati pa a danu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI