IGBA MẸRIN TI ỌRỌ OLUWO TI DA AWUYEWUYE SILẸ N'ILẸ YORUBA, ATI KAAKIRI AGBAYE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, February 16, 2020

IGBA MẸRIN TI ỌRỌ OLUWO TI DA AWUYEWUYE SILẸ N'ILẸ YORUBA, ATI KAAKIRI AGBAYE

Ninu ọba alade ilẹ Kaarọ ojiire, o fẹẹ ma si eleyi ti o sunmọ ọba ilu Iwo Abdulrasheed Adewale nibi ka jẹ olokiki.

Laye ode oni ti ti ọlaju oju opo ayelujara ti gbilẹ, iroyin orisirisi nipa Ọba yii lawọn eeyan ma n gbe kaakiri.

Pupọ ninu awọn iroyin wọnyi a maa ti ati ọwọ ọba Abdulrasheed wa nitori pe oun gaan ma n fi ọrọ si oju opo Instagram nipa ohun to ba n ṣẹlẹ ni ayika rẹ.

Ẹ jẹ ki a a ran ara wa leti diẹ ninu awọn iroyin to jẹyọ latara ọrọ ti ọba alade yi sti ọ ati awọnnkan to ṣe to mi igboro titi

#BI IYAWO OLUWO SE KO KURO N'ILE

Kabiesi ni idi ti oun fi kọ olori Chanel silẹ ni pe iyatọ n waye laarin awọn ti ko ṣee yanju.

Iroyin yii mi igboro titi ti awọn eeyan si bẹrẹ si ni sọ pe ko yẹ ki ọba Alade kọ iyawo rẹ silẹ.

Oluwo ko sọ ni pato ohun to fa ikọsilẹ naa lasiko yii ju pe ki awọn eeyan dẹkun bibu ọla fun Channel gẹgẹ bii iyawo oun mọ.
 Oluwo ati Chanel Chin
Ọmọ kan ni Chanel bí fún Oluwo, orukọ rẹ a si maa jẹ Oduduwa.

Olori Chanel Chin jẹ ọmọ orilẹ-ede Jamaica, baba rẹ si ni olorin takasufe ti ọpọ eeyan mọ si "Bobo Zaro."

'Èmi ni atọ́nà oyè Wàzírì nílẹ̀ Yorùbá'

Ọrọ o ṣe oye Waziri ilẹ Yoruba ko ṣe oye Waziri jẹ ọkan ti o da awuyewuye silẹ nigba ti Oluwo ilu Iwo sọ ọ.
Àkọlé àwòrán Oluwo tilu Iwo so pe oun fẹ di Ọba onilawani (Emir) ilẹ Yoruba
 Oluwo tilu Iwo
Ki lo ṣẹlẹ gaan? Oluwo kede pe oun fẹ danikan ṣe ifilọlẹ ẹni ti yoo jẹ Waziri fun gbogbo ilẹ Yoruba lalai fi ti awọn ọba toku tabi awọn onimọ Islam miran ṣe.

Ọrọ ko dun mọ awọn Alfa ilẹ Yoruba ninu ti o si di fa kin fa a laarin wọn ati Oluwo.

Lẹyin o rẹyin, Oluwo fi ẹni to wu u jẹ oye yi ti awọn Alfa si ni igbesẹ rẹ ko tọna nitori awọn onimọ́ ẹsin lo yẹ kio yan Waziri kii ṣe ọba.

Mo ti ṣetán láti daríi ìfẹ̀họ́nú hàn lòdì sí ìpànìyàn - Olúwó

Oluwo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrasheed Adewale Akanbi, sọ pe oun ti ṣe tan lati daríi ifẹhonuhan lodi si ipaniyan ati iwa ibajẹ ti o gbode kan lorilẹ-ede Naijiria.
 Oluwo of Iwoland, HIM Oba (Dr.) Abdulrosheed Adewale Akanbi
O bu ẹnu atẹ lu iha ti ijọba kọ si ọrọ ipaniyan ṣowo, ati pe pipaniyan fun ṣiṣe oogun owo buru ju iwa ijinigbe lọ.

Àkọlé àwòrán Oseni laanu wipe ijọba apapọ ko kọbi ara si iwa ipanijaye ti o gbode kan lorilẹ-ede wa

Oluwo tẹsiwaju pe, eto aabo ara ilu jẹ ojuṣe akọkọ fun ijọba.

O si bu ẹnu atẹ lu iwa ifẹmiṣofo ti o ti di tọrọ-kọbọ lorilẹ-ede yii.

Ẹ má gbé ẹ̀kú eégún 1960, tó ń rùn wọ ààfin mi

Lasiko ajọyọ ọdun Egungun to waye nilu Iwo ni Oluwo ti sọ ọrọ.
 Awọn egungun
Ninu ifọrọwanilẹwo pẹlu BBC Yoruba, Oluwo ni ọna ati gbe aṣa larugẹ ni ọdun egungun yii jẹ amọ oun ko ni gba ki egungun kankan rinrin idọti wọ aafin oun.


"Kosi eegun kan ti yoo wọ aafin mi to gbọdọ dọti. Kii ṣe wipe wọn yoo gbe ẹku 1960 wa, to ti dọti, to n run. Mo fẹ ki egungun to ba wa, jẹ nnkan iwuri fun awọn ọmọde ati awọn agba, ki gbogbo eeyan lee fi ọwọ kan awọn eegun yii."


Kabiyesi tẹsiwaju wi pe, ọdun egungun kii ṣe fun ibọriṣa, bikoṣe fun igbelaruge aṣa ati ere idaraya.

Lati BBC

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI