IDI TI MO ṢE PA OLOLUFẸ TI MO PADE LORI FESIBUUKU - AYEDERU WOLII SỌRỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, February 17, 2020

IDI TI MO ṢE PA OLOLUFẸ TI MO PADE LORI FESIBUUKU - AYEDERU WOLII SỌRỌ

Ayederu wolii kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Jide Ọlawale ti wọn lo o pa ololufẹ rẹ to pade lori ikanni ayelujara ti Fesibuuku, to si tun lọọ bo o mọlẹ.
 
A gbọ pe bi oṣu meloo kan sẹyin ni Ọlawale ati iyaale ile naa pade, ti wọn si bẹrẹ si i ba ara wọn sọrọ ifẹ lori fesibuuku naa, ko to o di pe wọn pinu lati ri ara wọn soju.

Wọn ni bi obinrin naa ṣe ile Ọlawale to wa ni Ifọ, ipinlẹ Ogun ni Ọlawale ti fi nnkan gba a, to si jẹ pe loju ẹsẹ lo ti di ọdẹ.
N'igba to ṣetan ni wọn ni Ọlawale dunbu obinrin naa, to si ge apa ati ori ẹ fun oogun owo, ko too di pe o lọ ọ sin ẹya ara toku sinu igbo.

Teṣan ọlọpaa ni Ọlawale wa titi d'asiko ti a fi kọ iroyin yii tan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI