Gomina Ṣeyi Makinde t'ipinlẹ Ọyọ ti paṣẹ pe k'awọn olukọnu ti ko din ni mẹtala lọọ jokoo sile titi d'igba ti inu oun yoo fi rọ lori ẹsun jibiti owo ti wọn fi kan wọn.
Awọn olukọni naa la gbọ pe ile-ẹkọ alakọọbẹrẹni wọn wa.
Alaga ẹgbẹ ajọ to n ri sọrọ eto ẹkọ, iyen Universal Basic Education Board (UBEB), Ọmọwe Nureni
Adeniran, la gbọ pe Gomina Makinde lo fun l'aṣẹ lati ja iwe lọọ gbe ile ẹ f'awọn eeyan naa.
AWIKONKO gbọ pe ṣe l'awọn olukọni naa n gba owo aitọ l'ọwọ awọn akẹkọọ, eyi ti wọn ni ko ba ofin ilana eto-ẹkọ mu. A tun gbọ pe ijọba ti gbe wọn kuro l'awọn ile-ẹkọ ti wọn ti n hu awọn iwa buruku yii, ṣugbọn ti wọn taku sibẹ.
Eyi lo mu ki ijọba gbe igbesẹ naa, ti wọn si ni dandan ni ki wọn lọọ kawọ pọyin rojọ niwaju igbimọ tijọba yan, ki wọn to le pada s'ẹnu iṣẹ wọn.
No comments:
Post a Comment