EYI NI BI WỌN TUN ṢE FẸ Ẹ BA TI TINUBU JẸ L'ỌDỌ BUHARI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, February 8, 2020

EYI NI BI WỌN TUN ṢE FẸ Ẹ BA TI TINUBU JẸ L'ỌDỌ BUHARI

Aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu APC l'orilẹ-ede Naijiria, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu ti pariwo sita pe ayederu iroyin l'awọn eeyan n gbe kaakiri n'ipa oun lati tako ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari, ati pe oun mọ pe awọn ọta oun lo wa n'idi ayederu iroyin naa.

Ẹ ṣọra fun iroyin ofege, emi o pe aarẹ Muhammadu Buhari ni alakatakiti ẹsin, eekan ninu ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Tinubu lo sọ bẹẹ.

Atẹjade kan lo lu ayelujara pa ninu eyi to fẹsun kan Tinubu pe o ṣapejuwe Buhari bi alakati ẹsun, ẹlẹyemẹta ati daaru daapọ lọdun 2013.

Atẹjade naa tun sọ pe Tinubu ni ti wọn ba gba Buhari laaye pẹrẹ, afaimọ ko maa pin orilẹede Naijiria, ati pe iwa ẹlẹmyamẹya Buhari le ṣakoba fun iṣọkan fun Naijiria.

Bi ẹ ko ba gbagbe Buhari dije fun ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu ANPP ninu idibo gbogbogbo ọdun 2003 ṣugbọn o fidi rẹmi, nigba ti Olusegun Obasanjo ẹgbẹ oṣelu PDP wọle ibo naa.

Tinubu naa dupo gomina ipinlẹ Eko fun saa keji lọdun naa labẹ asia ẹgbẹ oṣelu AD ninu eyi to ti jawe olubori.

Amọ, oludamọran fun Tinubu lori eto iroyin, Tunde Rahman sọ ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Ẹti pe ayederu iroyin lawọn kan n gbe kiri.

O ni awọn eeyan kan ti wọn koriira Tinubu lo wa nibi iroyin ofege naa, bakan naa lo beere pe ki ẹnikẹni to ba mọ ibi ti Tinubu ti sọrọ naa wi pe ko wa sọ.


"Asiwaju ko le sọ iru ọrọ bayii nipa Buhari laelae! Ati pe ko si ohun to le mu ki Tinubu sọ iru ọrọ yii nitori oun ati Buhari ko si ninu ẹgbẹ oṣelu kan naa, bẹẹ ni wọn o si nija ara wọn ninu,'' Ọgbẹni Rahman lo woye bẹẹ."

O ṣalaye siwaju sii pe ko ba tiẹ wu Tinubu gan an ki Buhari wọle ibo aarẹ ọdun 2003 nitori oun ti Obasanjo ṣe fun ipinlẹ Eko nigba to gbẹsẹ le owo to n wolẹ lati apo ijọba apapọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI