Nigba ti Kem Senou Pavel Daryl, ọmọ ọdun
mọkanlelogun to jẹ akọkọọ ọmọ orilẹede Cameroon to n gbe ni Jingshou lorilẹede
China ko arun Coronavirus, ko fọkan si i pe oun yoo pada kuro ni China koda bo
ba ṣeeṣe.
"Ohunkohun to ba ṣẹlẹ, mi o fẹ gbe arun naa
pada lọ si Afirika, o sọ ọrọ yii lati ileegbe wọn ni fasiti China nibi to ti n
gba itọju iyasọtọ ọlọjọ mẹrinla.
Apẹrẹ awọn nkan to n da a laamu ni iba, ikọ gbigbẹ
atawọn apẹrẹ to jọ mọ ti ni to ni aisan "flu".
"Nigba ti mo n lọ si ileewosan naa fun igba
akọkọ, ṣe ni mo n ronu iku mi ati bo ṣe maa ṣẹlẹ".
Fun ọjọ mẹtala naa, o wa ni iyasọtọ ni ile iwosan
abẹle kan ni orilẹede China. Awọn oogun antibiotics ati Melecine ti wọn fi n wo
alaisan HIV ni wọn n lo fun un to si bẹr si ni fara han pe ara rẹ ti n ya.
Ayẹwo inu ara ti wọn ṣe fun un ko fi ami aisan
kankan han. Oun lo wa di ọmọ ilẹ Afirika akọkọ ti awọn eeyan mọ ti o ko arun
coronavirus to si jẹ ẹni akọkọ to jaja bọ ninu rẹ.
Senou ni "mi o fẹ lọ sile ki n to pari ẹkọ mi.
Mi o ro pe idi kan wa lati pada lọ sile tori pe ijọba Chinese lo tọju gbogbo
owo ilera mi nile iwosan".
Ẹwẹ, orilẹede Egypt ti di orilẹede Afirika akọkọ ti
eeyan ti kọkọ ko arun coronavirus l'Afirika.
Awọn akọṣẹmọṣẹ ninu eto ilera ti kilọ pe o ṣeeṣe ki
awọn orilẹede ti eto ilera mẹhẹ maa tiraka gan pẹlu bi wọn ṣe le koju ajakalẹ
arun naa, eyi to ti pa eeyan to le ni ẹgbẹjọ ti awọn to le ni ẹgbẹrun
mejidinlaadọrin si ti ko arun naa paapaa ni apaa ilẹ China.
Lati: BBC
Lati: BBC
No comments:
Post a Comment