Bi ẹ ṣe n ka iroyin yii, inu ibẹrubojo ni gbogbo awọn Aarẹ orilẹ-ede ilẹ Adulawọ bayii pẹlu bi wọn ṣe ni aarun aṣekupani ojiji nni to n mi agbaye titi l'asiko yii, Coronavirus ṣe ti wọ ọkan lara awọn ilẹ adulawọ, iyẹn Egypt.
Orilẹ-ede Egypt lo kede ọrọ naa sita laipẹ yii wi pe aarun naa ti wọ ilẹ wọn.
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ eto ilera ilẹ Egypt, Khaled megahed lo f'idi iṣẹlẹe naa mulẹ wi pe ẹni ti wọn kofiri aarun n aa lara rẹ ki i ṣe ọmọ orilẹ-ede wọn, to si l'awọn ti n wa gbogbo ọna lati tọju ẹni ti wọn ri i lara rẹ.
No comments:
Post a Comment