Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọba Dapọ Abiọdun ti kede Ọgbẹni Emmanuel Ọladipupọ Adelẹyẹ gẹgẹ bi oluforukọ-silẹ (Registrar) fun ile-ẹkọ gbogboniṣe ti Moshood Abiọla to wa ni Ojere n'ilu Abẹokuta, ipinlẹ naa.
Gẹgẹ bi atẹjade ọjọ kọkanlelogun oṣu yii, eyi ti akọwe agba lẹka eto ẹkọ n'ipinlẹ na, A. O Ogunlẹyẹ bu ọwọ lu, eyi ti ẹda rẹ tẹ AWIKONKO lọwọ ṣe sọ, o ni loju ẹsẹ ni ọkunrin naa bẹrẹ iṣẹ rẹ.
Ọgbẹni Ọladipupọ Adelẹyẹ ni oluforukọ-silẹ tẹlẹ fun ile-ẹkọ naa, ti saa rẹ si pari lọjọ kẹta oṣu kejila ọdun 2019, ko to o di pe Gomina Abiọdun tun kede rẹ lati di ipo naa mu fun ọdun meji ati oṣu meje gbako.
Ọjọ karun oṣu karun ọdun yii la gbọ pe wọn yoo bẹrẹ si i ka iṣakoso rẹ, ti yoo si pari lọjọ kinni-in oṣu kejila ọdun 2022.
Emmanuel Ọladipupọ la gbọ pe wọn bi lọjọ kọkanlelogun oṣu kejila ọdun 1957 si idile Adelẹyẹ ni Oke-Ọdan, ijọba ibilẹ Yewa South, ipinlẹ Ogun.
Awọn ipa to ti ko lagboole eto ẹkọ kaakiri lo jẹ ki iṣẹ rẹ maa tọ ọ lẹyin titi di asiko yii.
No comments:
Post a Comment