Kete ti Aarẹ orilẹ-ede Naijiria,
Muhammadu Buhari fesi ni idahun si ikọlu ti awọn Boko Haram ṣe si awọn
arinrin-ajo ti ko din ni ọgbọn ni ipinlẹ Borno.
Ikọlu yii waye ni ilu Auno, to
jẹ opopona nla kan nipinlẹ Borno. Iroyin sọ pe 'ṣe ni awọn eeyan naa n sun lọwọ
nigba ti ọkọ duro lọna lati sinmi lawọn alakatakiti agbebọn ba dana sun wọn.
Aarẹ Buhari sọ pe ikọlu to waye
nirọlẹ ana jẹ eyi to ba ni lẹru pupọ ti ko si yẹ ko o waye. O tun wa sọ pe
ijọba apapọ, ijọba ipinlẹ Borno ati gbogbo ọmọ Naijirà to fi mọ awọn ọrẹ
Naijiria lo koro oju si iṣẹlẹ naa.
Aarẹ ni ijọba ko ni dẹkun
gbigbogun ti awọn alakatakiti agbebọn yii afi igba ti awọn ba bori wọn
patapata.
O ni ifarajin ijọba oun ṣi wa
lati da abo bo ẹmi awọn ọmọ Naijiria bẹẹ ni awọn ko si ni ṣina tabi sojo tori
awọn oniṣẹ laabi yii.
Tori naa, aarẹ ni oun ba awọn
ẹbi awọn to faragba ninu iṣẹlẹ naa o si fi da wọn loju pe ijọba oun yoo
tẹsiwaju lati maa funna mọ gbogbo igbesẹ aburu awn Boko Haram awọn yoo si mu u
wa sopin.
Keteti awọn ọmọ Naijiria foju
ganni eyi ni wọ́n han an mọ́ aarẹ Buhari lọwọ lori ayelujara.
Festus Keyamo (@alhassanixgeh)
mu wa si iranti awọn eeyan, fidio ifọrọwanilẹnuwo kan pẹlu aarẹ Muhammadu Buari
to ti wọn bi i nipa ohun ti ijọba rẹ yoo ṣe nipa abo ni Naijiria paapaa nigba
naa lọhun ti Boko Haram ṣẹṣẹ n yọju, aarẹ fi yanwọ ọrọ naa sẹyin eti ni to si
ni Boko HAram ko ja m nkankan.
Biliaminu Abdul Mujeeb Olaniyi
ni tirẹ ni kii ṣe nipa bibani kẹdun ati ka maa kọ ọrọ soju opo Twitter o, bi ko
ṣe pe awọn fẹ ri akitiyan kun akitiyan ati esi gidi.
Bash Mohammed oumar
(@amur_bash) fesi pe bo tilẹ jẹ pe alatilyin Buhari ni oun. O ran Bashir Ahmad
si ọga rẹ pe lootọ Buhari ti ṣe ọpọlọpọ lati tun orilede ṣe "ṣugbọn ni ti
abo, o ti ja wa kulẹ. O nilo lati ja fafa". O ni ki Bashir ran an leti pe
gbogbo eyi to ṣe ati eyi ti ko ṣe ni Ọlọrun yoo bere lọwọ rẹ.
Ẹwẹ lori ọrọ kan naa, ~Izge~⚡ (@shuaib_izge) ni oun kii ṣe alagabagebe oun ko si ni jẹ bẹẹ lailai. O ni aarẹ ana,
Goodluck loun maa da ẹbi le lori fun aile koju iṣoro abo ni ẹkun Ila oorun
Ariwa. Bẹẹ si ni o ni oun ko ni dakẹ bi Buhari gan naa ko ṣe ṣe nkankan.
Tosky Dada (@Dadasvc) fesi tirẹ
bii afiwe ni pe didoju ija kọ Boko Haram jẹ didoju ija kọ ẹkun ariwa Naijiria
ni.
Adam Mó (@adamm_mo) ni ọr oṣelu
lasan ni gbogbo ẹ tori ilu Auno ko ju irin kilomita marun un pere lọ lati
Bareke awọn ologun to to ọ̀wọ́ ogun mẹtalelọgbọn ni Maiduguri ti wọn si lee
koju ikọlu yii laarin iṣẹju perete ṣugbọn ko sẹni to yọju titi ti awọn Boko
Haram fi pa eeyan ọgbọn ti wọn si jo akẹkọọ fasiti Maiduguri meji di eeru.
Lati: BBC
No comments:
Post a Comment