Ṣe l’ọrọ di boolọ o yago l’ọna
laarọ oni n’igba ti wọn ni ado oloro ti wọn fi n pa ina ado oloro bu gbamu n’ilu
Ado Ekiti ti i ṣe olu-ilu ipinlẹ Ekiti.
Kọmiṣana Ọlọpaa ipinlẹ naa,
Ọgbẹni Asuquo Amba sọ fun BBC Yoruba pe lootọ ni ibugbamu kan waye ṣugbọn awọn
ko le sọ pato ohun ti o jẹ.
Ṣugbọn Ikechukwu sọ wi pe awọn
ni awọn ado oloro kan ti wọn fi n pa ina ibugbamu ado oloro ninu ile ti wọn n
ko nkan pamọ si.
Iṣẹlẹ naa waye ni adugbo kan to
wa ni agbegbe ile ijọba atij ti ipinlẹ Ekiti ni olu ilu ipinlẹ naa, Ado Ekiti.
Ṣe ni wọn gbọ gbamu lowurọ oni
ṣugbọn ko si ẹni kankan to fara pa tabi ba iṣẹlẹ naa rin bi o til jẹ wi pe o pa
ile ti wọn n ko nkan pamọ si lara.
Ọgbẹni Ikechukwu ni ikọ awọn ti
n ṣiṣẹ pọ lọwọ lọwọ pẹlu kọmisana lati mọ ohun to ṣẹlẹ gangan ati lati mu u
rọlẹ.
Kọmiṣana Ọlọpaa ipinlẹ Ekiti ni
orukọ ti awọn pe nkan ibugbamu yii ni ede to lee ye ara ilu ni awọn pe e yẹn
ṣugbọn awọn akọṣẹmọṣẹ ti n ṣe iṣẹ wọn tori naa ki awọn ara ilu ma bẹru.
A o maa mu ẹkunrẹrẹ iroyin naa
wa fun un yin bo ba ṣe n lọ.
Lati: BBC
No comments:
Post a Comment