Ilé ẹjọ́ àgbà orilẹ-èdè Nàìjíríà, ìyẹn Supreme Court tí sọ pé ohun tí ṣetan láti tún ẹjọ́ idibo gomina ipinlẹ Bayelsa gbọ́ l'Ọjọru tí í ṣe Wẹside ọ̀sẹ̀ yìí gbọ.
Ọjọ́ kẹtàlá oṣù yìí ni ile ẹjọ́ náà dá ẹjọ́ yìí, èyí tó fi pàṣẹ wí pé ẹgbẹ́ òṣèlú PDP lo jawe olubori látàrí bo ṣé sọ pé igbakeji gomina APC tí wọn lé dànù kò ṣe yẹ lẹni tó ń gbé àpótí ibo.
Bẹ ó bá gbàgbé, ọjọ́ kan ṣoṣo péré lo kú kí wọn búra fún gomina ẹgbẹ́ òṣèlú APC tí wọn dibó yan, ìyẹn David Lyon àti igbakeji rẹ, Biobarakuma Degi-Eremienyo kò tó o di pé ilé ẹ̀jọ àgbà pàṣẹ wí pé kí wọn lọ ọ rọ kún ilé.
Látìgbà náà ni David Lyon tí sọ pé òun kò ní í gba, àti pé igbakeji òun ló yẹ kí ilé ẹ̀jọ yọ dànù kí í ṣe òun.
Igbimọ onidajọ ẹlẹni márùn-ún tí Onidajọ Mary Peter-Odili lewaju rẹ to gbọ ẹ̀jọ náà lo pàṣẹ wí pé kí oludije sípò gomina lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP gba ipò náà.
No comments:
Post a Comment