Bo tilẹ jẹ pe pupọ awọn to gbọ
n’ipa baba arugbo ẹni aadọta ọdun kan, Kayọde Ọladẹhinde to fipa ja ibale
ọmọ-iyawo rẹ lo n ṣepe rabandẹ-rabandẹ fun baba naa, sibẹ ohun t’awọn kan n sọ
ni pe ọrọ baba naa ki i ṣ’oju lasan, ti wọn si lo ṣee ṣe ko lọwọ aye ninu.
Ọjọru tii ṣe Wẹsidee ijẹta la gbọ pe ọwọ ọlọpaa tẹ
Kayọde to n gbe l’adugbo Ọlọpẹ, iyẹn n’ilu Ogijo lori ẹsun yii, ti wọn si ni
diẹ lo ku k’awọn araalu luu lalubami.
A gbọ pe o ti pẹ ti Kayọde ti
wa l’ẹnu iwa yii ti pẹ, ṣugbọn to jẹ pe ọjọ Iṣẹgun tii ṣe Tuside la gbọ pe
aṣiri rẹ tu, ti wọn si lọọ fọrọ rẹ to awọn ọlọpaa leti ko too di pe wọn lọọ gbe
e.
AWIKONKO gbọ pe ṣe ni Kayọde
fun ọmọ naa ta a f’orukọ bo l’aṣiri loyun, ki aṣiri ma ba a tu lo mu ko tun ra oogun pe ko fi ṣe oyun
naa.
Oogun ti wọn loo fun ọmọ yii la
gbọ pe o yiwọ, ti wọn si ni ṣe ni ẹjẹ n da l’oju ara ọmọ yii, eyi gan an lo jẹ
ki mama rẹ mọ pe nnkan ti ṣẹlẹ, to si mu k’ọmọ naa jẹwọ pe ọkọ (mama) rẹ, iyẹn
Kayọde lo f’oun loyun, to si tun ṣẹ ẹ f’oun.
Idi ni yii ti wọn ni mama ọmọ
naa fi pariwo sita, t’awọn araadugbo si ni ko lọọ f’ọrọ naa to awọn ọlọpaa l’eti.
Wọn n’ibi t’awọn ọlọpaa ti lọọ gbe Kayọde lo ti bẹrẹ si i bẹbẹ wi pe iṣẹ eṣu
ni, ati pe oun ko mọ bo ṣe ṣẹlẹ.
Olu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun
to wa ni Eleweran, Abẹokuta la gbọ pe Kayọde wa bayii l’ẹka to n ri sọrọ lilo
awọn ọmọ n’ilokulo.
No comments:
Post a Comment