Olori kekere ti Alaafin Ọyọ, Ọba Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi kẹta
ti bi ọmọ ọkunrin tuntun.
Ọmọ tuntun ọhun ni iyawo kabiesi to kere julọ, Olori
Damilọla Adeyẹmi bi fun un.
Ninu ọrọ ti Olori naa fi s'oju opo Instagram rẹ lo ti
ki ara rẹ ku oriire, to si kọ akọle kan sibẹ pe "Mo ki ara mi ku ori ire,
ọmọ ọba ti de."
Ọkan lara awọn ọmọ Alaafin, Bunmi Labiyi fi idi ọrọ
naa mulẹ, ko da, ti Alaafin funra rẹ tun gbe e sọri ikanni ayelujara ti Fesibuuku rẹ laarọ oni.
O sọ pe ounjẹ gidi ti Alaafin n jẹ ati awọn ere
idaraya to ma n ṣe ṣeeṣe ko jẹ ohun to ṣi n fun baba ni okun bi ọdọmọde.
Bunmi ni "Baba mi ki n ṣaye bi awọn eeyan mii
ṣe ma n ṣe aye wọn. Kii jẹ ijẹkujẹ."
Bunmi tẹ siwaju pe Alaafin mọ irufẹ ounjẹ to yẹ ko
jẹ ati iru ounjẹ ti ko yẹ ko jẹ, koda o ni Kabiesi kii mu ẹlẹrindodo "Coca
Cola."
Bakan naa, o fi hande pe onimọ nipa ounjẹ jijẹ ni
Kabiesi to si maa n kilọ fun awọn eeyan nipa iru awọn akanpọ ounjẹ ti wọn n jẹ.
Ọmọ Ọba ṣalaye pe "Baba mi jẹ ẹni to mọ nipa ounjẹ gidi. Kii sọ pe nitori o jẹ Ọba Alaye ko wa maa jẹ ijẹkujẹ ki wọn eeyan le ri pe Alaafin lo n jẹun. Boya idi niyẹn ti Baba ṣi fi ni okun."
O pari ọrọ rẹ pe Kabiesi fẹran ere idaraya to bẹ to
fi jẹ pe o loju ọdọmọde to lee figa gbaga pẹlu Alaafin ti wọn ba bẹrẹ si n rin
papọ.
Lati: BBC
Lati: BBC
No comments:
Post a Comment