Laarọ oni l'awọn araalu n'ijọba ibilẹ kaakiri ipinlẹ Ọṣun paapaa l'awọn ijọba ibilẹ ti Oluwo tilu Iwo f'ẹsun kan wi pe wọn n ta ilẹ oun ṣe iwọde lọ si ọfiisi gomina ipinlẹ naa to wa ni Abẹrẹ, ipinlẹ Ọṣun.
Ko si ohun meji ti wọn ṣe iwọde ifẹhonu han le lori bi ko ṣe bi wọn ṣe n tako iwa ainitiju ti wọn ni Ọba AlbudulaRọṣheed Akanbi hu l'ọj'ọ Ẹti ọsẹ to kọja.
Wọn l'awọn ko le la oju silẹ k'ẹni ti ko yẹ ni ọba hu iwa ti ko ba ọmọluabi mu, k'awọn si ma le sọrọ lori ẹ. Bẹẹ ni wọn n rawọ ẹbẹ pe k'ijọba ba wọn le Ọba Akanbi danu, ki wọn si gba ade lori ẹ, tori pe ṣe lo n doju ti wọn kaakiri.
Ninu ọrọ ijọba ipinlẹ naa fi sita lo ti bu ẹnu atẹ lu iwa naa wi pe ko ba oju mu to l'awujọ oloye depodepo awujọ ọba alaye.
Atẹjade naa ti Kọmiṣanna f'eto iroyin ati ilani-lọyẹ, Arabinrin Funkẹ Ẹgbẹmọde fi sita lo ti jẹ ko di mimọ pe igbesẹ ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa, t'awọn yoo si jẹ k'awọn eeyan mọ ipinu ijọba lori ẹ.
O tun jẹ ko ye wa pe iwa idojuti gba a lo jẹ pe awọn ọba to yẹ ki wọn jẹ awokọṣe ati aṣiwaju n'idi aṣa ati iṣẹmbaye ni wọn n yọ ẹṣẹ si ara wọn n'ita gbangba, eyi to lo o ku diẹ kaato.
No comments:
Post a Comment