ATIJẸ LO LE ỌPỌLỌPỌ DE IDI IṢẸ SỌRỌSỌRỌ - ABASS ADEFULU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, February 11, 2020

ATIJẸ LO LE ỌPỌLỌPỌ DE IDI IṢẸ SỌRỌSỌRỌ - ABASS ADEFULU

Bi wọn ba n darukọ awọn ti iṣẹ redio ati tẹlifiṣan ye yekeyeke, ọkan pataki ninu wọn ni Abass Adefulu jẹ, tori pe yatọ si wi pe o lọọ kẹkọọ gboye n’ile-ẹkọ giga, o tun kẹkọọ yọranti l’ọdọ awọn agba ọjẹ n’idi iṣẹ naa, eyi to mu ko da yatọ l’aaarin awọn akẹgbẹ rẹ.

Ẹka ikẹkọọ eto ikansira-ẹni ati igbohunsafẹfẹ (Mass Communications) n’ile-ẹkọ gbogboniṣẹ ti Moshood Abiola to wa n’ilu Abẹokuta ni Abass Adefulu ti kẹkọọ gboye, ko too di pe o tun gba ọdọ ogbontarigi sọrọsọrọ nni, Oloye Yẹmi Ṣonde t’ọpọ mọ si Jigan Akala lọ lati tubọ ni imọ ni kikun si i.

Laipẹ yii ni Abass Adefulu ṣe ifọrọwerọ pẹlu awọn oniroyin kan, eyi to fi ranṣẹ si AWIKONKO, ninu ifọrọwerọ naa lo ti jẹ ko di mimọ pe ọpọ awọn sọrọsọrọ ori redio ati tẹlifiṣan l’asiko yii lo jẹ pe atijẹ lo sun wọn debẹ, nitori pe iṣẹ naa ko ye wọn yekeyekeye.

O ni ọpọ ninu wọn lo jẹ pe ki aye le mọ ọn lo ṣe n pe ara rẹ ni pedepede, ki i ṣe tori ipa to fẹẹ ko n’igbesi aye awọn araalu, ati idagbasoke to fẹ ẹ mu ba agbegbe ẹ.

Abass Adefulu t’awọn ololufẹ ẹ tun n pe ni Artunbi Pedepede sọ pe asawọ to pọ l’agboole sọrọsọrọ lo jẹ k’awọn kan maa f’oju tẹmbẹlu wọn, ṣugbọn to ni awọn ti iṣẹ naa ye l’awọn ololufẹ wọn mọ, ti wọn si mọ oṣuwọn t’onikaluku gbe.

Lara awọn ileeṣẹ redio ti Artunbi to bẹrẹ iṣẹ yii l’ọdun 2005 ti ṣ’eto daadaa ni OGBC (AM ati FM), Paramount FM, Smash FM, Roots FM to wa n’ilu Abẹokuta; Faaji FM, Radio Lagos, Choice FM to wa l’Ekoo ati RayPower FM to wa n’ilu Ibadan.

Yatọ si eyii, redio kan ti ina rẹ ṣẹṣẹ n jo daadaa n’ilu Abẹokuta bayii, iyẹn Splash FM ni Artunbi Pedepede tun wa bayii, to ti n ṣ’eto. Ilu Ibadan ni redio naa wa tẹlẹ ki wọn too tun ṣẹṣẹ da ẹka mi in s’ilu Abẹokuta.

Siwaju si i, Abass, iyẹn Baba Ibeji ninu ọrọ rẹ sọ pe ki i ṣe ohun (voice) gidi teeyan ba ni lo le jẹ ko ri ara rẹ gẹgẹ bi i sọrọsọrọ gidi, bi ko ṣe awọn agbekalẹ ati iṣẹ ọpọlọ to ba ni. O ni loootọ l’awọn kan ni ohun (voice) gidi, ṣugbọn awọn eto ti wọn n ṣe ko ba ilana eto igbohunsafẹfẹ mu rara.

O si jẹ ko di mimọ pe ohun mọ pe ileeṣẹ NBC to n ri sọrọ igbohunsafẹfẹ naa mọ awọn nnkan ti wọn le ṣe, ṣugbọn ti ko ti i ṣe e.

Bẹẹ lo gb’awọn to n f’oju sọna lati ṣe iṣẹ naa farabalẹ daadaa, ki wọn si gbiyanju lati tọ awọn agbaagba n’idi iṣẹ naa lọ lati le jẹ ki wọn da duro yatọ si awọn akẹgbẹ wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI