Bi iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ laipẹ yii ba fi le jẹ otitọ, a jẹ pe afi k'awọn mọlẹbi, ọrẹ ati ololufẹ Oloogbe AbbdulFatai Yusuff t'ọpọ mọ si Ọkọ Oloyun tete pe awọn ileeṣẹ eleto aabo, bi i Ọlọpaa, Sifu Difẹnsi, Fijilante at'awọn mi-in lati daabo bo awọn to fẹẹ ṣ'adura ọjọ mẹjọ fun un.
Bẹ o ba gbagbe, ọsẹ to kọja yii l'awọn agbebọn tẹnikẹni ko tii mọ d'asiko yii pa Ọkọ Oloyun s'oju ọna Igbọ-Ọra l'aski ti wọn lo n lọ ṣ'abẹwo si otẹẹli nla kan to n kọ lọwọ s'ilu ẹ ni Otu.
Bo tilẹ jẹ pe oriṣiriṣi aṣiri lo ti tu l'ẹyin iku Aarẹ ẹgbẹ awọn to n ṣe oogun ibilẹ l'orilẹ-ede Naijiria tẹlẹ naa, to si jẹ pe awọn ọlọpaa ti ṣeleri lati tọpinpin aṣiri iku to pa a lojiji.
Gbara ti Ọkọ Oloyun ti ku, t'iroyin si ti jade s'awọn eeyan, paapaa awọn ti wọn n f'owo dokoowo n'ileeṣẹ ẹ ti wọn pe ni Option C ti ya lọ si ọfiisi ẹ to wa ni Igando lati fẹhonu han wi pe awọn yoo gba owo wọn ni tipatipa.
T'awọn mi-in si n sọ pe to ba jẹ pe lara awọn ile ti ọkọ Oloyun kọ kaakiri orilẹ-ede Naijiria l'awọn ẹbi yoo ta fi san gbese ti ọkunrin naa jẹ wọn ko too ku, iyẹn ko kan awọn, ki owo awọn ṣaa ti tẹ wọn l'ọwọ ni, b'awọn ko ti ẹ ri ere ori owo wọn gba pada.
Ọhun ti wọn l'awọn ti ọkọ Oloyun jẹ l'owo n sọ n'igba ti wọn ko r'eeyan ba wọn sọrọ ti yoo tẹ wọn lọrun lori bi wọn yoo ṣe gba owo wọn ni pe ọjọ ti wọn yoo ba ṣ'eto adura ikẹhin fun oloogbe naa ni gbegede yoo gbina.
Bo tilẹ jẹ pe a ko tii le f'idi rẹ mulẹ, ṣugbọn lara awọn ahesọ to tẹ AWIKONKO lọwọ bayii ni pe awọn kan l'ara awọn ti wọn n f'owo dokoowo ti pe ara wọn jọ lati da eto adura naa ru, ko da, ti wọn ni wọn yoo lu gbogbo ẹni to ba duro lati ṣe adura naa.
O ṣee ṣe ko jẹ pe ọrọ naa ti to awọn mọlẹbi ati ọrẹ Oloogbe naa leti tẹlẹ, to si mu ki wọn ma fi adireesi si fọto eto adura naa ti wọn gbe jade sita, lati ma jẹ ki ọpọ eeyan mọ ibi ti eto adura naa yoo ti waye.
Ko pẹ ti iroyin naa tun fi jade sita wi pe ile-igbafẹ Ọkọ Oloyun ti wọn pe ni Fun City to wa ni Hotel Bus-stop, Igando l'Ekoo ni eto adura naa yoo ti waye, ti wọn l'awọn to f'owo dokoowo ti n gbaradi lati faraya yanna-yanna l'ọjọ naa.
No comments:
Post a Comment