WỌN NI ÀÀRẸ Ọ̀NÀ KAKANFO Ń RONÚ KIRI BAYII, NÍTORÍ ỌMỌṢẸ RẸ TO GBE OWÓ SÁLỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, January 31, 2020

WỌN NI ÀÀRẸ Ọ̀NÀ KAKANFO Ń RONÚ KIRI BAYII, NÍTORÍ ỌMỌṢẸ RẸ TO GBE OWÓ SÁLỌ


Ààrẹ Ọna Kakanfo ilẹ̀ Yorùbá, Iba Abiọdun Ige Gani Adams là gbọ pé inú ìrònú ńlá gidi lo wá báyìí, lórí bí ọkàn lára àwọn amugbalẹgbẹ tó gbé owó rẹ salọ lójijì, tí wọn kò sì tíì rí títí d'asiko tá a ṣ'akojọpọ ìròyìn yìí tán.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ní kii ṣe owó tí amugbalẹgbẹ Ààrẹ Gani Adams tí wọn pé orúkọ rẹ ni Fẹmi Agunbiade gbé salọ lọ ń ka bàbà náà lara, ṣùgbọ́n tí wọn ní Fẹmi lọ fẹ́ràn ju nínú àwọn tó ń bá a ṣíṣẹ, pàápàá bo tún ṣe jẹ́ mọlẹbi rẹ.

AWIKONKO gbọ pé ó ti lè l'ọdun mẹẹdogun tí Gani Adams tí mú Fẹmi s'ọdọ láti máa tọju ẹ gẹ́gẹ́ bí ọmọ, tí wọ́n sì ni bo ṣe jẹ́ mọlẹbi rẹ lo jẹ́ kó finu tán án kọjá sísọ, kò dá tí wọn ní gbogbo àṣírí rẹ lo mọ.

Ààrẹ Gani Adams tó tún jẹ́ olórí ẹgbẹ́ ajijangbara fún ilẹ̀ Yorùbá káàkiri àgbáyé, ìyẹn Oodua Peoples Congress (OPC) là gbọ pé ó gbé owó tí kò dín ni miliọnu méjì (2.1) náírà fún Fẹmi wí pé kò lọọ fi san owó gbọngan ayẹyẹ to tí ṣe ayẹyẹ ọdún méjì lórí ipò AARẸ ỌNA KAKANFO.

Wọn ní lára owó náà ni wọn tún ti ní kí Fẹmi gbé lọ fún ọkàn lára àwọn tó ń ṣadura fún Iba Gani Adams to ń gbe ni Ugbe-Akoko n'ipinlẹ Ọṣun, tí a sì gbọ pé láti bí ọsẹ mélòó kan sẹ́yìn tí wọn tí gbé owó náà fún un lo tí pòórá bí iso.

Lára àwọn tó gbé iṣẹlẹ náà sì wà létí jẹ́ kó ye wá pé l'atigba tí Fẹmi tí na pápá bora ni inu Iba Adams kò ti dùn mọ rárá, tí wọn sì ni ṣe ló ń kanra mọ gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ rẹ.

Wọn ní òjìji ni iṣẹlẹ náà bá Ààrẹ nítorí pé ẹni tó n'ifẹ sì ju ni, tí kò sì f'igba kan rí là àlá wípé Fẹmi yóò dá òun.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun t'awọn kan ń sọ ní pe Fẹmi kò jẹbi lórí bo se gbé owó náà salọ, torí pé kò mọ koko ohun tó ń tẹle Ààrẹ fún, tá a sì gbọ pé ọpọ ìgbà ni wọn ti dá ẹrú rẹ síta n'ile tó ń yà gbé.

A tún gbọ pé iwọnba owó tí Fẹmi ń rí l'ọdọ Iba Adams kò too gbọ bukata ara rẹ pẹlu tí ẹbi ẹ, tí wọn sì ni ṣe ló ń tọrọ owó àti oúnjẹ káàkiri.

Síbẹ̀, ohun t'awọn kan sọ ní pe alaimọ-oore ni Fẹmi fún ìwà tó hu náà, nítorí pé kò sí nnkan tó béèrè lọ́wọ́ Aare Gani Adams tiyẹn kii fún un.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI