Wọn ni ki Buhari kọ'we f'ipo silẹ
Diẹ lo ku k'awọn aṣofin agba l'Abuja lu ara wọn
l'Ọjọru Wẹsidee anaa n'igba ti olori awọn Sẹnetẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, Sẹnetọ Enyinnaya Abaribe ni, eto aabo
orilẹ-ede yii ti wa buru kọja sisọ, to si ni ki Aarẹ Muhammadu Buhari kọ'we
f'ipo silẹ kiakia.
Enyinnaya ni, iṣẹ akọkọ ni pe gbogbo ijọba ni aabo ẹmi ati
dukia gbọdọ jẹ logun, ṣugbọn to ni Buhari ti padanu l'ori eyi. O ni, ipaniyan kaakiri
orilẹ-ede yii ti wa kọja nnkan mi-in bayii, to si ni apa Buhari ko ka a mọ.
O
ni, ohun to n bi oun ninu ju ni irọ t'ijọba Buhari fẹran lati maa pa ninu iwe
iroyin lati tan awọn araalu jẹ.
O ni, ijọba Buhari ti kede pe, awọn ti r'ẹyin ẹgbẹ
Boko Haram, ṣugbọn to l'awọn iṣẹlẹ to n ṣẹlẹ bayii ti fi han pe, baba nla irọ
ni. O ni, laipẹ yii l'awọn ọmọ Naijiria yoo lọ ko o l'oju pe ko kọ'we f'ipo rẹ silẹ
tabi k'awọn sọ oun at'awọn ti wọn n ṣe ijọba l'okuta.
Lẹsẹkẹsẹ ni awọn aṣofin APC ti da a l'ohun, ti
Sẹnetọ Abdullah Adamu lati ipinlẹ Nassarawa ni, ọrọ ti ko n'itumọ lo n sọ, ti ọrọ si d'ariwo nla t'awọn Sẹnetọ naa fẹ ẹ lu ara wọn si ko too di pe Aarẹ wọn,
Sẹnetọ Ahamad Lawan sare da si i.
Ẹ gbọ, ṣe ki Aarẹ Muhammadu Buhari maa ba iṣẹ rẹ lọ
tabi ko kọ'we f'ipo silẹ?
No comments:
Post a Comment