Pupọ àwọn tó
gbọ nípa ṣọọṣi kan tí wọn tí ń tà pátá ìgbàlà f'awọn obìnrin lo ṣí ń yà l'ẹnu
títí d'asiko tá a ṣ'akojọpọ ìròyìn yìí tan, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kẹtikẹti l' àwọn
obìnrin ṣọọṣi náà ra pátá ọ̀hún.
Oludasilẹ
ṣọọṣi náà tí wọn pé ní Touch for Recovery Outreach International, Pasitọ J. S.
Yusuff là gbọ pé ó ṣ'agbekalẹ pátá náà gẹ́gẹ́ bí ìwòsàn àti ìdáǹdè f'awọn tó
bá ń wá itusilẹ, pàápàá àwọn obìnrin.
Ọ̀ṣẹ̀ to kọjá
yìí l'ariwo ṣọọṣi náà tó wà n'ilu Abuja gbà gbogbo ilu.
Pasitọ Yusuff
ni Ọlọ́run ló pá a láṣẹ f'òun láti gbàdúrà s'awọn pátá náà f'awọn obìnrin tí
wọ́n bá ń wá ọkọ, àti pé kii ṣé pátá nìkan ni Pasitọ náà kéde rẹ fún títa, wọn
loo tún kéde beresiya, ìyẹn Bra náà pẹ̀lú.
AWIKONKO gbọ
pé láti lè jẹ ki ọpọ àwọn ọlọmọge tó wà nínú ṣọọṣi náà tètè rí ọkọ fẹ l'ọdun
2020 yìí ló fi ṣ'agbekalẹ pátá àti beresiya náà, tó sì paa láṣẹ fún wọn pé wọn
gbọ́dọ̀ bá Ọlọ́run d'owó pọ
N'igba to ń
mú ẹsẹ̀ Bíbélì kan jáde láti inú ìwé Númérì 23:20, èyí tó fi gbé pátá àti
beresiya ìyanu náà jáde, Yusuff jẹ kò di mímọ̀ pé ọpọ pátá àti beresiya náà
l'oun tí tẹ àwòrán òun sì, kí wọn lé dá ojúlówó mọ.
Bákan náà ni
Pasitọ yìí tún jẹ́ kó yẹ àwọn ọmọ ìjọ rẹ pé àwọn pátá àtàwọn beresiya yìí tún ń
ṣíṣẹ ìwòsàn kúrò nínú onírúurú àìsàn àti àrùn.
No comments:
Post a Comment