ỌRỌ BURUKU T'OUN T'ẸRIN: NNKAN ỌMỌKUNRIN POORA MỌ BABA ARUGBO L'ABẸ NITA GBANGBA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, January 24, 2020

ỌRỌ BURUKU T'OUN T'ẸRIN: NNKAN ỌMỌKUNRIN POORA MỌ BABA ARUGBO L'ABẸ NITA GBANGBA

Bi ẹlẹkun ṣe n sunkun, bẹẹ ni ẹlẹrin n r'ẹrin niluu Umuahia, ipinlẹ Abia l'Ọjọbọ Tọside ana, nigba ti baba agba kan pariwo sita wi pe nnkan ọmọkunrin toun fi n ṣ'agbara ti poora m'oun l'abẹ l'ọsan gangan.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, Papa Ejima ni wọn pe orukọ baba agba ti wọn ni nnkan ọmọkunrin ẹ poora laarin ero, ti wọn si lo n fẹsun kan gendekunrin kan ta a ko mọ oruko rẹ titi di asiko ti a fi kọ iroyin yii tan wi pe o mọ nipa bi kinni oun ṣe d'ọfẹ lojiji.

Adugbo kan ti wọn pe ni Oboro, loju ọna Niger, nilu Umuahia niṣẹlẹ kayeefi naa ti waye. Wọn ni Papa Ejima sọ pe ẹni toun fẹsun kan naa lo fi ara gba oun lojiji, to si jẹ pe asiko naa ni kinni abẹ oun d'awati.

Bi ọrọ naa ṣe di ariwo la gbo pe o mu k'awọn eeyan to wa nitosi pe le wọn lori nibi ti wọn ti n fa a, to si ku diẹ k'awọn tinu n bi pinnu lati dana sun ọkunrin naa bi ko ba tete wa nnkan ṣe si i, ṣugbọn ti wọn loo sọ pe baba oun to wa lagbegbe Niger yoo ba a da a pada bi wọn ba le ṣe suuru.

Ko pẹ ti wọn ni awọn eeyan n gbero lati dana sun ọkunrin yii, t'awọn ọlọpaa fi de bẹ, ti wọn si ko awọn mejeeji kuro laarin wọn lati lọọ yanju ẹ.

 

 
 
 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI